II. A. Ọba 8

8
Obinrin Ará Ṣunemu náà Pada
1ELIṢA si wi fun obinrin na, ọmọ ẹniti o ti sọ di ãyè, wipe, Dide, si lọ, iwọ ati ile rẹ, ki o si ṣe atipo nibikibi ti iwọ ba le ṣe atipo: nitoriti Oluwa pe ìyan: yio si mu pẹlu ni ilẹ, li ọdun meje.
2Obinrin na si dide, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun na: on si lọ pẹlu ile rẹ̀, nwọn si ṣe atipo ni ilẹ awọn ara Filistia li ọdun meje.
3O si ṣe lẹhin ọdun meje, ni obinrin na pada bọ̀ lati ilẹ awọn ara Filistia: on si jade lọ lati kepè ọba nitori ile rẹ̀ ati nitori ilẹ rẹ̀.
4Ọba si mba Gehasi iranṣẹ enia Ọlọrun na sọ̀rọ, wipe, Mo bẹ̀ ọ, sọ gbogbo ohun nla, ti Eliṣa ti ṣe fun mi.
5O si ṣe bi o ti nrò fun ọba bi o ti sọ okú kan di ãyè, si kiyesi i, obinrin na, ẹniti a sọ ọmọ rẹ̀ di ãyè kepè ọba nitori ilẹ rẹ ati nitori ile rẹ̀. Gehasi si wipe, Oluwa mi, ọba, eyi li obinrin na, eyi si li ọmọ rẹ̀ ti Eliṣa sọ di ãyè.
6Nigbati ọba si bère lọwọ obinrin na, o rohin fun u. Ọba si yàn iwẹ̀fa kan fun u, wipe, Mu ohun gbogbo ti iṣe ti rẹ̀ pada fun u, ati gbogbo erè oko lati ọjọ ti o ti fi ilẹ silẹ titi di isisiyi.
7Eliṣa si wá si Damasku; Benhadadi ọba Siria si nṣe aisàn; a si sọ fun u, wipe, Enia Ọlọrun de ihinyi.
8Ọba si wi fun Hasaeli pe, Mu ọrẹ lọwọ rẹ, si lọ ipade enia Ọlọrun na, ki o si bère lọwọ Oluwa lọdọ rẹ̀, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi?
9Bẹ̃ni Hasaeli lọ ipade rẹ̀, o si mu ọrẹ li ọwọ rẹ̀, ani ninu gbogbo ohun rere Damasku, ogoji ẹrù ibakasiẹ, o si de, o si duro niwaju rẹ̀, o si wipe, Ọmọ rẹ Benhadadi ọba Siria rán mi si ọ, wipe, Emi o ha sàn ninu arùn yi?
10Eliṣa si wi fun u pe, Lọ, ki o si sọ fun u pe, Iwọ iba sàn nitõtọ: ṣugbọn Oluwa ti fi hàn mi pe, nitõtọ on o kú.
11On si tẹ̀ oju rẹ̀ mọ ọ gidigidi, titi oju fi tì i; enia Ọlọrun na si sọkun.
12Hasaeli si wipe, Ẽṣe ti oluwa mi fi nsọkun? On si dahùn pe, Nitoriti mo mọ̀ ibi ti iwọ o ṣe si awọn ọmọ Israeli: awọn odi agbara wọn ni iwọ o fi iná bọ̀, awọn ọdọmọkunrin wọn ni iwọ o fi idà pa, iwọ o si fọ́ ọmọ wẹwẹ́ wọn tútu, iwọ o si là inu awọn aboyun wọn.
13Hasaeli si wipe, Ṣugbọn kinla? Iranṣẹ rẹ iṣe aja, ti yio fi ṣe nkan nla yi? Eliṣa si dahùn wipe, Oluwa ti fi hàn mi pe, iwọ o jọba lori Siria.
14Bẹ̃li o lọ kuro lọdọ Eliṣa, o si de ọdọ oluwa rẹ̀; on si wi fun u pe, Kini Eliṣa sọ fun ọ? On si dahùn wipe, O sọ fun mi pe, Iwọ o sàn nitõtọ.
15O si ṣe ni ijọ keji ni o mu aṣọ ti o nipọn, o kì i bọ̀ omi, o si tẹ́ ẹ le oju rẹ̀, bẹ̃li o kú. Hasaeli si jọba nipò rẹ̀.
Jehoramu Ọba Juda
(II. Kro 21:1-20)
16Ati li ọdun karun Joramu, ọmọ Ahabu ọba Israeli, Jehoṣafati jẹ ọba Juda: nigbana Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
17Ẹni ọdun mejilelọgbọn li o jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.
18O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, bi ile Ahabu ti ṣe: nitori ọmọbinrin Ahabu li o nṣe aya rẹ̀; on si ṣe ibi niwaju Oluwa.
19Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa Juda run, nitori Dafidi iranṣẹ rẹ̀, bi o ti ṣe ileri fun u, lati fun u ni imọlẹ ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọjọ gbogbo.
20Li ọjọ rẹ̀ ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro li abẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.
21Bẹ̃ni Joramu rekọja siha Sairi, ati gbogbo awọn kẹkẹ́ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o yi i ka: ati awọn olori awọn kẹkẹ́: awọn enia si sá wọ inu agọ wọn.
22Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna.
23Iyokù iṣe Joramu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
24Joramu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Ahasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Ahasaya Ọba Juda
(II. Kro 22:1-6)
25Li ọdun kejila Joramu ọmọ Ahabu ọba Israeli, Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.
26Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba li ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ a si ma jẹ Ataliah, ọmọbinrin Omri ọba Israeli.
27O si rìn li ọ̀na ile Ahabu, o si ṣe ibi niwaju Oluwa, bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o nṣe ana ile Ahabu.
28On si lọ pẹlu Joramu ọmọ Ahabu si ogun na ti o mba Hasaeli ọba Siria jà ni Ramoti-Gileadi; awọn ara Siria si ṣa Joramu li ọgbẹ́.
29Joramu ọba si pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ti ṣa a ni Rama, nigbati o mba Hasaeli ọba Siria ja. Ahasiah ọmọ Jehoramu ọba Juda sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu ọmọ Ahabu ni Jesreeli nitoriti o nṣe aisàn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. A. Ọba 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀