II. Sam 11
11
Dafidi ati Batiṣeba
1O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu.
2O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò.
3Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti?
4Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀.
5Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù.
6Dafidi si ranṣẹ si Joabu, pe, Ran Uria ará Hitti si mi. Joabu si ran Uria si Dafidi.
7Nigbati Uria si de ọdọ rẹ̀, Dafidi si bi i li ere alafia Joabu, ati alafia awọn enia na, ati bi ogun na ti nṣe.
8Dafidi si wi fun Uria pe, Sọkalẹ lọ si ile rẹ, ki o si wẹ ẹsẹ rẹ. Uria si jade kuro ni ile ọba, onjẹ lati ọdọ ọba wá si tọ̀ ọ lẹhin.
9Ṣugbọn Uria sùn li ẹnu-ọ̀na ile ọba lọdọ gbogbo iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
10Nigbati nwọn si sọ fun Dafidi pe, Uria kò sọkalẹ lọ si ile rẹ̀, Dafidi si wi fun Uria pe, Ṣe ọ̀na àjo ni iwọ ti wá? eha ti ṣe ti iwọ kò fi sọkalẹ lọ si ile rẹ?
11Uria si wi fun Dafidi pe, Apoti-ẹri, ati Israeli, ati Juda joko ninu agọ; ati Joabu oluwa mi, ati awọn iranṣẹ oluwa mi wà ni ibudo ni pápa: emi o ha lọ si ile mi, lati jẹ ati lati mu, ati lati ba obinrin mi sùn? bi iwọ ba wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti mbẹ lãye, emi kì yio ṣe nkan yi.
12Dafidi si wi fun Uria pe, Si duro nihin loni, li ọla emi o si jẹ ki iwọ ki o lọ. Uria si duro ni Jerusalemu li ọjọ na, ati ijọ keji.
13Dafidi si pè e, o si jẹ, o si mu niwaju rẹ̀; o si mu ki ọti ki o pa a: on si jade li alẹ lọ si ibusùn rẹ̀ lọdọ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀, kò si sọkalẹ lọ si ile rẹ̀.
14O si ṣe li owurọ Dafidi si kọwe si Joabu, o fi rán Uria.
15O si kọ sinu iwe pe, Fi Uria siwaju ibi tí ogun gbe le, ki ẹ si bó o silẹ, ki nwọn le kọ lù u, ki o si kú.
16O si ṣe nigbati Joabu ṣe akiyesi ilu na, o si yàn Uria si ibi kan ni ibi ti on mọ̀ pe awọn alagbara ọkunrin mbẹ nibẹ.
17Awọn ọkunrin ilu na si jade wá, nwọn si ba Joabu jà: diẹ si ṣubu ninu awọn enia na ninu awọn iranṣẹ Dafidi; Uria ará Hitti si kú pẹlu.
18Joabu si ranṣẹ o si rò gbogbo nkan ogun na fun Dafidi.
19O si paṣẹ fun iranṣẹ na pe, Nigbati iwọ ba si pari ati ma rò gbogbo nkan ogun na fun ọba,
20Bi o ba ṣe pe, ibinu ọba ba fàru, ti on si wi fun ọ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi sunmọ ilu na lati ba wọn jà, ẹnyin kò mọ̀ pe nwọn o tafà lati ori odi wá?
21Tali o pa Abimeleki ọmọ Jerubbeṣeti? Ki iṣe obinrin li o yi okuta ọlọ lù u lati ori odi wá, ti o si kú ni Tebeṣi? ẽha ti ri ti ẹnyin fi sunmọ odi na? Iwọ o si wi fun u pe, Uria iranṣẹ rẹ ará Hitti kú pẹlu.
22Iranṣẹ na si lọ, o si wá, o si jẹ gbogbo iṣẹ ti Joabu ran a fun Dafidi.
23Iranṣẹ na si wi fun Dafidi pe, Nitõtọ awọn ọkunrin na lagbara jù wa lọ, nwọn si jade tọ̀ wa wá ni pápa, awa si tẹle wọn titi nwọn fi de ẹhìn odi.
24Awọn tafàtafa si ta si iranṣẹ rẹ lati ori odi wá, diẹ ninu awọn iranṣẹ ọba si kú, iranṣẹ rẹ Uria ará Hitti si kú pẹlu.
25Dafidi si wi fun iranṣẹ na pe, Bayi ni iwọ o wi fun Joabu pe, Máṣe jẹ ki nkan yi ki o buru li oju rẹ, nitoripe idà a ma jẹ li ọtun li òsi, mu ijà rẹ le si ilu na, ki o si bì i ṣubu: ki iwọ ki o si mu u lọkàn le.
26Nigbati aya Uria si gbọ́ pe Uria ọkọ rẹ̀ kú, o si gbawẹ̀ nitori ọkọ rẹ̀.
27Nigbati awẹ̀ na si kọja tan, Dafidi si ranṣẹ, o si mu u wá si ile rẹ̀, on si wa di aya rẹ̀, o si bi ọmọkunrin kan fun u. Ṣugbọn nkan na ti Dafidi ṣe buru niwaju Oluwa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.