II. Sam 16
16
Dafidi ati Siba
1NIGBATI Dafidi si fi diẹ kọja ori oke na, si wõ, Siba iranṣẹ Mefiboṣeti si mbọ̀ wá ipade rẹ̀, ti on ti kẹtẹkẹtẹ́ meji ti a ti dì li asá, ati igba iṣu akara li ori wọn, ati ọgọrun ṣiri ajara gbigbẹ, ati ọgọrun eso ẹrùn, ati igò ọti-waini kan.
2Ọba si wi fun Siba pe, Kini wọnyi? Siba si wipe, Kẹtẹkẹtẹ wọnyi ni fun awọn ara ile ọba lati ma gùn; ati akara yi, ati eso ẹrùn yi ni fun awọn ọdọmọdekunrin lati jẹ; ati ọti-waini yi ni fun awọn alãrẹ ni ijù lati mu.
3Ọba si wipe, Ọmọ oluwa rẹ da? Siba si wi fun ọba pe, Wõ, o joko ni Jerusalemu; nitoriti o wipe, Loni ni idile Israeli yio mu ijọba baba mi pada fun mi wá.
4Ọba si wi fun Siba pe, Wõ, gbogbo nkan ti iṣe ti Mefiboṣeti jẹ tirẹ. Siba si wipe, Mo tũba, jẹki nri ore-ọfẹ loju rẹ, oluwa mi, Ọba.
Dafidi ati Ṣimei
5Dafidi ọba si de Bahurimu, si wõ, ọkunrin kan ti ibẹ̀ jade wá, lati idile Saulu wá, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Ṣimei, ọmọ Gera: o si nyan ẹ̃bu bi o ti mbọ̀.
6O si sọ okuta si Dafidi, ati si gbogbo iranṣẹ Dafidi ọba, ati si gbogbo awọn enia, gbogbo awọn alagbara ọkunrin si wà lọwọ ọtún rẹ̀ ati lọwọ osì rẹ̀.
7Bayi ni Ṣimei si wi nigbati o nyan ẽbu, Jade, jade, iwọ ọkunrin ẹjẹ, iwọ ọkunrin Beliali.
8Oluwa mu gbogbo ẹjẹ idile Saulu pada wá si ori rẹ, ni ipo ẹniti iwọ jọba; Oluwa ti fi ijọba na le Absalomu ọmọ rẹ lọwọ: si wõ, ìwa buburu rẹ li o mu eyi wá ba ọ, nitoripe ọkunrin ẹjẹ ni iwọ.
9Abiṣai ọmọ Seruia si wi fun ọba pe, Ẽṣe ti okú ajá yi fi mbu oluwa mi ọba? jẹ ki emi kọja, emi bẹ̀ ọ, ki emi si bẹ́ ẹ li ori.
10Ọba si wipe, Kili emi ni fi nyin ṣe, ẹnyin ọmọ Seruia? jẹ ki o ma bu bẹ̃, nitoriti Oluwa ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, Nitori kini iwọ fi ṣe bẹ̃?
11Dafidi si wi fun Abiṣai, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rẹ̀, si jẹ ki o ma yan ẽbu; nitoripe Oluwa li o fi rán an.
12Bọ́ya Oluwa yio wo ipọnju mi, Oluwa yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rẹ̀ loni.
13Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nlọ li ọ̀na, Ṣimei si nrìn li ẹba oke ti o wà li ẹgbẹ rẹ̀, o si nyan ẽbu bi o ti nlọ, o si nsọ ọ li okuta, o si nfún erupẹ.
14Ọba, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀ si wá ti awọn ti ãrẹ̀, nwọn si simi nibẹ.
15Absalomu ati gbogbo awọn enia, awọn ọkunrin Israeli si wá si Jerusalemu, Ahitofeli si wà pẹlu rẹ̀.
Absalomu ní Jerusalẹmu
16O si ṣe, nigbati Huṣai ará Arki, ọrẹ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai si wi fun Absalomu pe, Ki ọba ki o pẹ, ki ọba ki o pẹ.
17Absalomu si wi fun Huṣai pe, Ore rẹ si ọ̀rẹ rẹ ni eyi? ẽṣe ti iwọ kò ba ọrẹ rẹ lọ?
18Huṣai si wi fun Absalomu pe, Bẹ̃kọ nitori ẹniti Oluwa, ati gbogbo awọn enia yi, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ba yàn, tirẹ̀ li emi o jẹ, on li emi o si ba joko.
19Ẹwẹ̀, tani emi o si sìn? kò ha yẹ ki emi ki o ma sìn niwaju ọmọ rẹ̀? gẹgẹ bi emi ti nsìn ri niwaju baba rẹ, bẹ̃li emi o ri niwaju rẹ.
20Absalomu si wi fun Ahitofeli pe, Ẹ ba ara nyin gbìmọ ohun ti awa o ṣe.
21Ahitofeli si wi fun Absalomu pe, Wọle tọ awọn obinrin baba rẹ lọ, awọn ti o fi silẹ lati ma ṣọ ile, gbogbo Israeli yio si gbọ́ pe, iwọ di ẹni-irira si baba rẹ, ọwọ́ gbogbo awọn ti o wà lọdọ rẹ yio si le.
22Nwọn si tẹ agọ kan fun Absalomu li orile; Absalomu si wọle tọ awọn obinrin baba rẹ̀ li oju gbogbo Israeli.
23Imọ̀ Ahitofeli ti ima gbà nijọ wọnni, o dabi ẹnipe enia mbere nkan li ọwọ́ Ọlọrun: bẹ̃ni gbogbo ìmọ Ahitofeli fun Dafidi ati fun Absalomu si ri.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 16: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: