II. Sam 17
17
Huṣai Ṣi Absalomu lọ́nà
1AHITOFELI si wi fun Absalomu pe, Emi o si yan ẹgbãfa ọkunrin emi o si dide, emi o si lepa Dafidi li oru yi.
2Emi o si yọ si i nigbati ãrẹ̀ ba mu u ti ọwọ́ rẹ̀ si ṣe alaile, emi o si dá ipaiya bá a; gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ yio si sa, emi o si kọlu ọba nikanṣoṣo:
3Emi o si mu gbogbo awọn enia pada sọdọ rẹ; ọkunrin na ti iwọ nwá si ri gẹgẹ bi ẹnipe gbogbo wọn ti pada: gbogbo awọn enia yio si wà li alafia.
4Ọrọ na si tọ loju Absalomu, ati li oju gbogbo awọn agbà Israeli.
5Absalomu si wipe, Njẹ̀ pe Huṣai ará Arki, awa o si gbọ́ eyi ti o wà li ẹnu rẹ̀ pẹlu.
6Huṣai si de ọdọ Absalomu, Absalomu si wi fun u pe, Bayi ni Ahitofeli wi, ki awa ki o ṣe bi ọ̀rọ rẹ̀ bi? bi kò ba si tọ bẹ̃, iwọ wi.
7Huṣai si wi fun Absalomu pe, Imọ̀ ti Ahitofeli gbà nì, ko dara nisisiyi.
8Huṣai si wipe, Iwọ mọ̀ baba rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe alagbara ni nwọn, nwọn si wà ni kikoro ọkàn bi amọ̀tẹkun ti a gbà li ọmọ ni igbẹ: baba rẹ si jẹ jagunjagun ọkunrin, kì yio ba awọn enia na gbe pọ̀ li oru.
9Kiyesi i o ti fi ara rẹ̀ pamọ nisisiyi ni iho kan, tabi ni ibomiran: yio si ṣe, nigbati diẹ ninu wọn ba kọ ṣubu, ẹnikẹni ti o ba gbọ́ yio si wipe, Iparun si mbẹ ninu awọn enia ti ntọ̀ Absalomu lẹhin.
10Ẹniti o si ṣe alagbara, ti ọkàn rẹ̀ si dabi ọkàn kiniun, yio si rẹ̀ ẹ: nitori gbogbo Israeli ti mọ̀ pe alagbara ni baba rẹ, ati pe, awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ jẹ alagbara.
11Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na.
12Awa o si yọ si i nibikibi ti awa o gbe ri i, awa o si yi i ka bi irì iti sẹ̀ si ilẹ̀: ani ọkan kì yio kù pẹlu rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀.
13Bi o ba si bọ si ilu kan, gbogbo Israeli yio si mu okùn wá si ilu na, awa o si fà a lọ si odo, titi a kì yio fi ri okuta kekeke kan nibẹ.
14Absalomu ati gbogbo ọkunrin Israeli si wipe, Ìmọ Huṣai ara Arki sàn jù ìmọ Ahitofeli lọ. Nitori Oluwa fẹ lati yi ìmọ rere ti Ahitofeli po, nitori ki Oluwa ki o le mu ibi wá sori Absalomu.
Dafidi sá fún ewu tí ń bọ̀
15Huṣai si wi fun Sadoku ati fun Abiatari awọn alufa pe, Bayi bayi ni Ahitofeli ti ba Absalomu ati awọn agbà Israeli dámọran; bayi bayi li emi si damọràn.
16Nitorina yara ranṣẹ nisisiyi ki o si sọ fun Dafidi pe, Máṣe duro ni pẹtẹlẹ ijù nì li alẹ yi, ṣugbọn yara rekọja, ki a má ba gbe ọba mì, ati gbogbo awọn enia ti o mbẹ lọdọ rẹ̀.
17Jonatani ati Ahimaasi si duro ni Enrogeli; ọdọmọdebirin kan si lọ, o si sọ fun wọn; awọn si lọ nwọn sọ fun Dafidi ọba nitoripe ki a má ba ri wọn pe nwọn wọ ilu.
18Ṣugbọn ọdọmọdekunrin kan ri wọn, o si wi fun Absalomu: ṣugbọn awọn mejeji si yara lọ kuro, nwọn si wá si ile ọkunrin kan ni Bahurimu, ẹniti o ni kanga kan li ọgbà rẹ̀, nwọn si sọkalẹ si ibẹ.
19Obinrin rẹ̀ si mu nkan o fi bo kanga na, o si sa agbado sori rẹ̀; a kò si mọ̀.
20Awọn iranṣẹ Absalomu si tọ obinrin na wá ni ile na, nwọn si bere pe, Nibo ni Ahimaasi ati Jonatani gbe wà? obinrin na si wi fun wọn pe, Nwọn ti goke rekọja iṣan odo nì. Nwọn si wá wọn kiri, nwọn kò si ri wọn, nwọn si yipada si Jerusalemu.
21O si ṣe, lẹhin igbati nwọn yẹra kuro tan, awọn si jade kuro ninu kanga, nwọn si lọ, nwọn si rò fun Dafidi ọba, nwọn si wi fun Dafidi pe, Dide ki o si goke odo kánkán: nitoripe bayi ni Ahitofeli gbìmọ si ọ.
22Dafidi si dide, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, nwọn si goke odo Jordani: ki ilẹ to mọ́, ẹnikan kò kù ti kò goke odo Jordani.
23Nigbati Ahitofeli si ri pe nwọn kò fi ìmọ tirẹ̀ ṣe, o si di kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si dide, o lọ ile rẹ̀, o si palẹ ile rẹ̀ mọ, o si pokùnso, o si kú, a si sin i si iboji baba rẹ̀.
24Dafidi si wá si Mahanaimu. Absalomu si goke odo Jordani, on, ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli pẹlu rẹ̀.
25Absalomu si fi Amasa ṣe olori ogun ni ipò Joabu: Amasa ẹniti iṣe ọmọ ẹnikan, orukọ ẹniti a npè ni Itra, ara Israeli, ti o wọle tọ Abigaili ọmọbinrin Nahaṣi, arabinrin Seruia, iyá Joabu.
26Israeli ati Absalomu si do ni ilẹ Gileadi.
27O si ṣe, nigbati Dafidi si wá si Mahanaimu, Ṣobi ọmọ Nahaṣi ti Rabba ti awọn ọmọ Ammoni, ati Makiri ọmọ Ammieli ti Lodebari, ati Barsillai ara Gileadi ti Rogelimu,
28Mu akete, ati ago, ati ohun-elo amọ̀, ati alikama, ati ọkà, ati iyẹfun, ati agbado didin, ati ẹ̀wa, ati erẽ, ati ẹ̀wa didin.
29Ati oyin, ati ori-amọ, ati agutan, ati wàrakasi malu, wá fun Dafidi, ati fun awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ lati jẹ: nitoriti nwọn wi pe, ebi npa awọn enia, o si rẹ̀ wọn, orungbẹ si ngbẹ wọn li aginju.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Sam 17: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: