II. Tim 1

1
1PAULU, Aposteli Kristi Jesu nipa ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi ileri ìye ti mbẹ ninu Kristi Jesu,
2Si Timotiu, ọmọ mi olufẹ ọwọn: Ore-ọfẹ, ãnu, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Kristi Jesu Oluwa wa.
Ìdúpẹ́ ati Ọ̀rọ̀ Ìwúrí
3Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, ti emi nsìn lati ọdọ awọn baba mi wá ninu ẹri-ọkan funfun, pe li aisimi li emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi,
4T'ọsan t'oru li emi njaìyà ati ri ọ, ti mo nranti omije rẹ, ki a le fi ayọ̀ kún mi li ọkàn;
5Nigbati mo ba ranti igbagbọ́ ailẹtan ti mbẹ ninu rẹ, eyiti o kọ́ wà ninu Loide iya-nla rẹ, ati ninu Eunike iya rẹ; mo si gbagbọ pe, o mbẹ ninu rẹ pẹlu.
6Nitori idi eyi ni mo ṣe nran ọ leti pe ki iwọ ki o mã rú ẹ̀bun Ọlọrun soke eyiti mbẹ ninu rẹ nipa gbigbe ọwọ mi le ọ.
7Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti ọkàn ti o yè kõro.
8Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun;
9Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye,
10Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere,
11Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ.
12Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì.
13Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.
14Ohun rere nì ti a ti fi le ọ lọwọ, pa a mọ́ nipa Ẹmí Mimọ́ ti ngbe inu wa.
15Eyi ni iwọ mọ̀, pe gbogbo awọn ti o wà ni Asia yipada kuro lẹhin mi; ninu awọn ẹniti Figellu ati Hermogene gbé wà.
16Ki Oluwa ki o fi ãnu fun ile Onesiforu; nitoriti ima tù mi lara nigba pupọ̀, ẹ̀wọn mi kò si tì i loju:
17Ṣugbọn nigbati o wà ni Romu, o fi ẹsọ̀ wá mi, o si ri mi.
18Ki Oluwa ki o fifun u ki o le ri ãnu lọdọ Oluwa li ọjọ nì: iwọ tikararẹ sá mọ̀ dajudaju iye ohun ti o ṣe fun mi ni Efesu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Tim 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀