Dan 2
2
Àlá Nebukadnessari
1ATI li ọdun keji ijọba Nebukadnessari, Nebukadnessari lá alá nipa eyi ti ọkàn rẹ̀ kò fi le ilẹ ninu rẹ̀, ti orun si dá loju rẹ̀.
2Nigbana ni ọba paṣẹ pe, ki a pè awọn amoye ati ọlọgbọ́n, ati awọn oṣó, ati awọn Kaldea wá, lati fi alá ọba na hàn fun u. Bẹ̃ni nwọn si duro niwaju ọba.
3Ọba si wi fun wọn pe, mo lá alá kan, ọkàn mi kò si le ilẹ lati mọ̀ alá na.
4Nigbana ni awọn Kaldea wi fun ọba li ede awọn ara Siria pe, Ki ọba ki o pẹ́: rọ́ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ, awa o si fi itumọ̀ na hàn.
5Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn.
6Ṣugbọn bi ẹnyin ba fi alá na hàn, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, ẹnyin o gba ẹ̀bun ati ọrẹ ati ọlá nla li ọwọ mi: nitorina, ẹ fi alá na hàn fun mi, ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu.
7Nwọn tun dahùn nwọn si wipe, Ki ọba ki o rọ alá na fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, awa o si fi itumọ̀ rẹ̀ hàn.
8Ọba si dahùn o wi pe, emi mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin fẹ mu akoko pẹ, nitoriti ẹnyin ri pe nkan na lọ li ori mi.
9Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu.
10Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri.
11Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara.
12Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run.
13Nigbana ni aṣẹ jade lọ pe, ki nwọn ki o pa awọn amoye; nwọn si nwá Danieli pẹlu awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lati pa wọn.
Ọlọrun fi Àlá Ọba ati Ìtumọ̀ Rẹ̀ Han Daniẹli
14Nigbana ni Danieli fi ìmọ ati ọgbọ́n dahùn wi fun Arioku, ti iṣe balogun ẹṣọ ọba, ẹniti nlọ pa awọn amoye Babeli.
15O dahùn o si wi fun Arioku, balogun ọba pe, Ẽṣe ti aṣẹ fi yá kánkán lati ọdọ ọba wá bẹ̃? Nigbana ni Arioku fi nkan na hàn fun Danieli.
16Nigbana ni Danieli wọle lọ, o si bère lọwọ ọba pe, ki o fi akokò fun on, o si wipe, on o fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba.
17Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
18Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli.
19Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun.
20Danieli dahùn o si wipe, Olubukún ni orukọ Ọlọrun titi lai; nitori tirẹ̀ li ọgbọ́n ati agbara.
21O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:
22O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà.
23Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.
Daniẹli Rọ́ Àlá Ọba, Ó sì Sọ Ìtumọ̀ Rẹ̀
24Nigbana ni Danieli wọle tọ Arioku lọ, ẹniti ọba yàn lati pa awọn ọlọgbọ́n Babeli run, o si lọ, o si wi fun u bayi pe; Máṣe pa awọn ọlọgbọ́n Babeli run: mu mi lọ siwaju ọba, emi o si fi itumọ na hàn fun ọba.
25Nigbana li Arioku yara mu Danieli lọ siwaju ọba, o si wi bayi fun u pe, Mo ri ọkunrin kan ninu awọn ọmọ igbekun Juda, ẹniti yio fi itumọ na hàn fun ọba.
26Ọba dahùn o si wi fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari pe, Iwọ le fi alá ti mo la hàn fun mi, ati itumọ rẹ̀ pẹlu?
27Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba.
28Ṣugbọn Ọlọrun kan mbẹ li ọrun ti o nfi aṣiri hàn, ẹniti o si fi hàn fun Nebukadnessari ohun ti mbọ wá ṣe ni ikẹhin ọjọ. Alá rẹ, ati iran ori rẹ lori akete rẹ, ni wọnyi;
29Ọba, iwọ nronu lori akete rẹ, ohun ti yio ṣe lẹhin ọla, ati ẹniti o nfi aṣiri hàn funni mu ọ mọ̀ ohun ti mbọ wá ṣe.
30Ṣugbọn bi o ṣe temi ni, a kò fi aṣiri yi hàn fun mi nitori ọgbọ́n ti emi ni jù ẹni alãye kan lọ, ṣugbọn nitori ki a le fi itumọ na hàn fun ọba, ati ki iwọ ki o le mọ̀ èro ọkàn rẹ.
31Iwọ ọba nwò, si kiyesi, ere nla kan. Ere giga yi, ti didan rẹ̀ pọ̀ gidigidi, o duro niwaju rẹ, ìrí rẹ̀ si ba ni lẹ̀ru gidigidi.
32Eyi ni ere na; ori rẹ̀ jẹ wura daradara, aiya ati apa rẹ̀ jẹ fadaka, inu ati ẹ̀gbẹ rẹ̀ jẹ idẹ,
33Itan rẹ̀ jẹ irin, ẹsẹ rẹ̀ si jẹ apakan irin, apakan amọ̀.
34Iwọ ri titi okuta kan fi wá laisi ọwọ, o si kọlu ere na lẹsẹ rẹ̀, ti iṣe ti irin ati amọ̀, o si fọ́ wọn tũtu.
35Nigbana li a si fọ irin, amọ̀, idẹ, fadaka ati wura pọ̀ tũtu, o si dabi iyangbo ipaka nigba ẹ̀run; afẹfẹ si gbá wọn lọ, ti a kò si ri ibi kan fun wọn mọ́: okuta ti o si fọ ere na si di òke nla, o si kún gbogbo aiye.
36Eyiyi li alá na; awa o si sọ itumọ rẹ̀ pẹlu niwaju ọba.
37Iwọ ọba, li ọba awọn ọba: nitori Ọlọrun ọrun ti fi ijọba, agbara, ati ipá, ati ogo fun ọ.
38Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi.
39Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye.
40Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna.
41Ati gẹgẹ bi iwọ ti ri ẹsẹ ati ọmọkasẹ ti o jẹ apakan amọ̀ amọkoko, ati apakan irin, ni ijọba na yio yà si ara rẹ̀; ṣugbọn ipá ti irin yio wà ninu rẹ̀, niwọn bi iwọ ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀.
42Gẹgẹ bi ọmọkasẹ na ti jẹ apakan irin ati apakan amọ̀, bẹ̃li apakan ijọba na yio lagbara, apakan yio si jẹ ohun fifọ.
43Ati gẹgẹ bi iwọ si ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀, nwọn o da ara wọn pọ mọ iru-ọmọ enia, ṣugbọn nwọn kì yio fi ara wọn mọ ara wọn, gẹgẹ bi irin kì ti idapọ mọ amọ̀.
44Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai.
45Gẹgẹ bi iwọ si ti ri ti okuta na wá laisi ọwọ lati òke wá, ti o si fọ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wura wọnni tutu; Ọlọrun titobi ti fi hàn fun ọba, ohun ti mbọ wá ṣe lẹhin ọla: otitọ si li alá na, itumọ rẹ̀ si daju.
Ọba fún Daniẹli ní Ẹ̀bùn
46Nigbana ni Nebukadnessari, ọba, wolẹ o si doju rẹ̀ bolẹ, o si fi ori balẹ fun Danieli, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o ṣe ẹbọ-ọrẹ ati õrùn didùn fun u.
47Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn.
48Nigbana li ọba sọ Danieli di ẹni-nla, o si fun u li ẹ̀bun nla pupọ, o si fi i jẹ olori gbogbo igberiko Babeli, ati olori onitọju gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli.
49Danieli si bère lọwọ ọba, o si fi Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego jẹ olori ọ̀ran igberiko Babeli; ṣugbọn Danieli joko li ẹnu-ọ̀na ãfin ọba.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: