Dan 3
3
Nebukadinessari Pàṣẹ pé kí Gbogbo Eniyan máa Sin Ère Wúrà tí ó gbé kalẹ̀
1NEBUKADNESSARI ọba, si yá ere wura kan, eyi ti giga rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa: o si gbé e kalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, ni igberiko Babeli.
2Nigbana ni Nebukadnessari ọba, ranṣẹ lọ ipè awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, ati awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko, lati wá si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari ọba, gbé kalẹ.
3Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.
4Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo,
5Pe, akokò ki akokò ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki ẹnyin wolẹ, ki ẹ si tẹriba fun ere wura ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
6Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.
7Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Àìgbọràn Kan Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta
8Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn.
9Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.
10Iwọ ọba ti paṣẹ pe, bi ẹnikẹni ba ti gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki o wolẹ ki o si tẹriba fun ere wura na.
11Ẹnikẹni ti kò ba si wolẹ ki o tẹriba, ki a gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.
12Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.
13Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba.
14Nebukadnessari dahùn, o si wi fun wọn pe, otitọ ha ni, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, pe, ẹnyin kò sìn oriṣa mi, ẹ kò si tẹriba fun ere wura na ti mo gbé kalẹ?
15Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi.
16Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dahùn, nwọn si wi fun ọba pe, Nebukadnessari, kò tọ si wa lati fi èsi kan fun ọ nitori ọ̀ran yi.
17Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba.
18Ṣugbọn bi bẹ̃kọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa kì yio sìn oriṣa rẹ, bẹ̃li awa kì yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.
Wọ́n Dá Ẹjọ́ Ikú fún Àwọn Ọ̀rẹ́ Daniẹli Mẹtẹẹta
19Nigbana ni Nebukadnessari kún fun ibinu, àwọ oju rẹ̀ si yipada si Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego: o dahùn, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o da iná ileru na ki õru rẹ̀ gboná niwọn igba meje jù bi a ti imu u gboná ri lọ.
20O si paṣẹ fun awọn ọkunrin ani awọn alagbara julọ ninu ogun rẹ̀ pe ki nwọn ki o di Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ki nwọn ki o si sọ wọn sinu iná ileru na ti njo.
21Nigbana ni a dè awọn ọkunrin wọnyi ti awọn ti agbáda, ṣokoto, ati ibori wọn, ati ẹwu wọn miran, a si gbé wọn sọ si ãrin iná ileru ti njo.
22Nitorina bi aṣẹ ọba ti le to, ati bi ileru na si ti gboná gidigidi to, ọwọ iná na si pa awọn ọkunrin ti o gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, lọ.
23Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo.
24Nigbana ni Nebukadnessari ọba warìri o si dide duro lọgan, o dahùn, o si wi fun awọn ìgbimọ rẹ̀ pe, awọn ọkunrin mẹta kọ a gbé sọ si ãrin iná ni didè? Nwọn si dahùn wi fun ọba pe, Lõtọ ni ọba.
25O si dahùn wipe, Wò o, mo ri ọkunrin mẹrin ni titu, nwọn sì nrin lãrin iná, nwọn kò si farapa, ìrisi ẹnikẹrin si dabi ti Ọmọ Ọlọrun.
A Dá Àwọn Ọkunrin Mẹtẹẹta sílẹ̀ a sì gbé wọn ga
26Nigbana ni Nebukadnessari sunmọ ẹnu-ọ̀na ileru na o dahùn o si wipe, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun Ọga-ogo, ẹ jade ki ẹ si wá. Nigbana ni Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, jade lati ãrin iná na wá.
27Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn.
28Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn.
29Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi.
30Nigbana ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego leke ni igberiko Babeli.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: