Dan 4
4
Àlá Keji tí Nebukadinesari Lá
1NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin.
2O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn.
3Ami rẹ̀ ti tobi to! agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ ti pọ̀ to! ijọba ainipẹkun ni ijọba rẹ̀, ati agbara ijọba rẹ̀ ati irandiran ni.
4Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi:
5Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi.
6Nitorina ni mo ṣe paṣẹ lati mu gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli wá niwaju mi, ki nwọn ki o le fi itumọ alá na hàn fun mi.
7Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi.
8Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe,
9Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀.
10Bayi ni iran ori mi lori akete mi; mo ri, si kiyesi i, igi kan duro li arin aiye, giga rẹ̀ si pọ̀ gidigidi.
11Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye.
12Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara.
13Mo ri ninu iran ori mi lori akete mi, si kiye si i, oluṣọ, ani ẹni mimọ́ kan sọkalẹ lati ọrun wá;
14O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:
15Ṣugbọn, fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ ninu ilẹ, ani pẹlu ide ninu irin ati idẹ ninu koriko tutu igbẹ; si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki o si ni ipin rẹ̀ ninu koriko ilẹ aiye pẹlu awọn ẹranko:
16Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀.
17Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.
18Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.
Daniẹli Túmọ̀ Àlá náà
19Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.
20Igi ti iwọ ri ti o si dagba, ti o si lagbara, eyi ti giga rẹ̀ kan ọrun, ti a si ri i de gbogbo aiye;
21Eyi ti ewe rẹ̀ lẹwà, ti eso rẹ̀ si pọ̀, ninu eyi ti onjẹ si wà fun gbogbo ẹda, labẹ eyi ti awọn ẹranko igbẹ ngbe, lori ẹka eyi ti awọn ẹiyẹ oju-ọrun ni ibugbe wọn.
22Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.
23Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,
24Ọba, itumọ rẹ̀ li eyi, ati eyiyi li aṣẹ Ọga-ogo, ti o wá sori ọba, oluwa mi:
25Nwọn o le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ nwọn o si mu ki iwọ ki o jẹ koriko bi malu, nwọn o si mu ki iri ọrun sẹ̀ si ọ lara, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe Ọga-ogo ni iṣe olori ni ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.
26Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori.
27Nitorina ọba, jẹ ki ìmọran mi ki o jẹ itẹwọgba lọdọ rẹ, ki o si fi ododo ja ẹ̀ṣẹ rẹ kuro, ati aiṣedẽde rẹ nipa fifi ãnu hàn fun awọn talaka; bi yio le mu alafia rẹ pẹ.
28Gbogbo eyi de ba Nebukadnessari, ọba.
29Lẹhin oṣu mejila, o nrin kiri lori ãfin ijọba Babeli.
30Ọba si dahùn, o wipe, Ko ṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ́ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi?
31Bi ọ̀rọ na si ti wà lẹnu ọba, ohùn kan fọ̀ lati ọrun wá, pe, Nebukadnessari, ọba, iwọ li a sọ fun; pe, a gba ijọba kuro lọwọ rẹ.
32A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.
33Ni wakati kanna ni nkan na si ṣẹ si Nebukadnessari, a si le e kuro larin enia, o si jẹ koriko bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, titi irun ori rẹ̀ fi kún gẹgẹ bi iyẹ idì, ẽkana rẹ̀ si dabi ti ẹiyẹ.
Nebukadinesari Yin Ọlọrun Lógo
34Li opin igba na, Emi Nebukadnessari si gbé oju mi soke si ọrun, oye mi si pada tọ̀ mi wá, emi si fi ibukún fun Ọga-ogo, mo yìn, mo si fi ọla fun ẹniti o wà titi lailai, ẹniti agbara ijọba rẹ̀ jẹ ijọba ainipẹkun, agbara ati ijọba rẹ̀ lati irandiran.
35Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?
36Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ.
37Nisisiyi, emi Nebukadnessari yìn, mo si gbé Ọba ọrun ga, mo si fi ọlá fun u, ẹniti gbogbo iṣẹ rẹ̀ iṣe otitọ, ati gbogbo ọ̀na rẹ̀ iṣe idajọ: ati awọn ti nrìn ninu igberaga, on le rẹ̀ wọn silẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan 4: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: