Dan Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìtàn inú ìwé yìí ṣẹlẹ̀ ní àkókò ọba kan tí kò ka ẹ̀sìn kún nǹkankan, tí ó sì ń fìyà jẹ àwọn tí wọn ń ṣe ẹ̀sìn. Ẹni tí ó kọ ìwé yìí ń fi ọkàn àwọn eniyan rẹ̀ balẹ̀ pẹlu ìrètí pé Ọlọrun yóo gba ìjọba lọ́wọ́ aninilára tí ó wà lórí oyè, yóo sì fi ìjọba náà lé àwọn eniyan rẹ̀ lọ́wọ́, a máa fi ìtàn ati àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọrun gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀.
Ìpín meji pataki ni ìwé yìí ní: (1) Àwọn ìtàn nípa Daniẹli ati àwọn tí wọ́n jọ wà ní ìgbèkùn tí wọ́n sì ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn nípa igbagbọ ati ìgbọràn sí Ọlọrun. Àkókò ìjọba ọba ti ìlú Babiloni ati ti Pasia ni wọ́n kọ àwọn ìtàn wọnyi. (2) Oríṣìíríṣìí ìran ni Daniẹli ń rí tí ó dúró fún àpẹẹrẹ ìjọba ati ìṣubú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè. Orílẹ̀-èdè àwọn ará Babiloni ni orílẹ̀-èdè àkọ́kọ́. Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú tí yóo dé bá ọba aninilára tí kò ka ẹ̀sìn kún, ati ìṣẹ́gun tí àwọn eniyan Ọlọrun yóo ní.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Daniẹli ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 1:1—6:28
Àwọn ìran tí Daniẹli rí 7:1—11:45
a. Ẹranko mẹrin 7:1-28
b. Àgbò ati ewúrẹ́ 8:1—9:27
d. Iranṣẹ òde ọ̀run 10:1—11:45
e. Àkókò ìkẹyìn 12:1-13
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Dan Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: