Esek 48

48
1WỌNYI si ni orukọ awọn ẹ̀ya na. Lati opin ariwa titi de ọwọ́ ọ̀na Hetlonu, bi a ba nlọ si Hamati, Hasaenani, leti Damasku niha ariwa, de ọwọ́ Hamati; wọnyi sa ni ihà rẹ̀ ni ila-õrun ati iwọ-õrun; ipin kan fun Dani.
2Ati ni àgbegbe Dani, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Aṣeri.
3Ati ni àgbegbe Aṣeri, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Naftali.
4Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse.
5Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu.
6Ati ni àgbegbe Efraimu, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Reubeni.
7Ati ni àgbegbe Reubeni, lati ihà ila-õrun, ani titi de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Juda.
8Ati ni àgbegbe Juda, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun ni yio jẹ ọrẹ ti ẹnyin o ta, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ije ni ibú, ati ni gigùn, bi ọkan ninu awọn ipin iyokù, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.
9Ọrẹ ti ẹnyin o si ta fun Oluwa yio jẹ ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú.
10Ati fun wọn, ani fun awọn alufa, ni ọrẹ mimọ́ yi yio jẹ; ni ihà ariwa, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-marun ni ibú, ati ni ihà gusu, ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn: ibi mimọ́ yio si wà lãrin rẹ̀.
11Yio jẹ ti awọn alufa ti a yà si mimọ́, ninu awọn ọmọ Sadoku; ti nwọn ti pa ilàna mi mọ, ti nwọn kò si ṣìna ni iṣìna awọn ọmọ Israeli, bi awọn Lefi ti ṣìna.
12Ọrẹ ilẹ ti a si ta yi, yio jẹ ohun mimọ́ julọ fun wọn li àgbegbe awọn Lefi.
13Ati ni ikọjusi àgbegbe awọn alufa, ni awọn Lefi yio ni ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbã-marun ni ibú: gigùn gbogbo rẹ̀ yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ati ibú rẹ̀, ẹgbã-marun.
14Nwọn kì yio si tà ninu rẹ̀, nwọn kì yio si fi ṣe paṣiparọ, bẹ̃ni nwọn kì yio si fi akọ́so ilẹ na si ọwọ́ ẹlomiran, nitoripe o jẹ mimọ́ fun Oluwa.
15Ati ẹgbẹ̃dọgbọn ti o kù ni ibú, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun na, yio jẹ ibi aimọ́ fun ilu-nla na, fun ibugbe, ati fun àgbegbe: ilu-nla na yio si wà lãrin rẹ̀.
16Wọnyi ni yio si jẹ iwọ̀n rẹ̀; ni ihà ariwa, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, ati ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta.
17Awọn àgbegbe ilu-nla na yio jẹ niha ariwa, ãdọtalerugba, ati nihà gusu, ãdọtalerugba ati nihà ila-õrun, ãdọtalerugba, ati nihà iwọ-õrun, ãdọtalerugba.
18Ati iyokù ni gigùn, ni ikọjusi ọrẹ ti ipin mimọ́ na, yio si jẹ ẹgbã-marun nihà ila-õrun, ati ẹgbã-marun nihà iwọ-õrun: yio si wà ni ikọjusi ọrẹ ipin mimọ́ na, ati ibisi rẹ̀ yio jẹ fun onjẹ fun awọn ti nsìn ni ilu-nla na.
19Awọn ti mba nsìn ilu-nla na yio si ma sìn i, lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli.
20Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na.
21Ati iyokù yio jẹ ti olori, ni ihà kan, ati nihà keji ti ọrẹ mimọ́ na, ati ti ini ibi nla na, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ọrẹ ti àgbegbe ila-õrun, ati nihà iwọ-õrun ni ikọjusi ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun, nihà àgbegbe iwọ-õrun, ni ikọjusi awọn ipin ti olori: yio si jẹ ọrẹ mimọ́ na; ibi mimọ́ ile na, yio si wà lãrin rẹ̀.
22Ati lati ini awọn Lefi, ati lati ini ti ilu-nla na, lãrin eyiti iṣe ti olori, lãrin àgbegbe Juda, ati lãrin àgbegbe Benjamini, yio jẹ ti olori.
23Ati fun awọn ẹ̀ya iyokù, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Benjamini ipin kan.
24Ati ni àgbegbe Benjamini, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Simeoni ipin kan.
25Ati ni àgbegbe Simeoni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Issakari ipin kan.
26Ati ni àgbegbe Issakari, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Sebuloni ipin kan.
27Ati ni àgbegbe Sebuloni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Gadi ipin kan.
28Ati ni àgbegbe Gadi, ni ihà gusu si gusu, àgbegbe na yio jẹ lati Tamari de omi ijà ni Kadeṣi, ati si odò, titi de okun nla.
29Eyi ni ilẹ ti ẹnyin o fi ìbo pin ni ogún fun awọn ẹ̀ya Israeli, wọnyi si ni ipin wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.
30Wọnyi si ni ibajade ti ilu-nla na lati ìha ariwa, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta oṣùwọn.
31Awọn bode ilu-nla na yio jẹ gẹgẹ bi orukọ awọn ẹ̀ya Israeli: bodè mẹta nihà ariwa, bodè Reubeni ọkan, bodè Juda ọkan, bodè Lefi ọkan.
32Ati ni ihà ila-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta: ati bodè mẹta; ati bode Josefu ọkan, bode Benjamini ọkan, bodè Dani ọkan.
33Ati ni ihà gusu, ẹgbã-meji, o le ẹ̃dẹgbẹta ìwọn: ati bodè mẹta; bodè Simeoni ọkan, bodè Issakari ọkan, bodè Sebuloni ọkan.
34Ni ihà iwọ-õrun, ẹgbã-meji o le ẹ̃dẹgbẹta, pẹlu bodè mẹta wọn; bodè Gadi ọkan, bodè Aṣeri ọkan, bodè Naftali ọkan.
35O jẹ ẹgbã-mẹsan ìwọn yika: orukọ ilu-nla na lati ijọ na lọ yio ma jẹ, Oluwa mbẹ nibẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek 48: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀