Deu 10
10
Mose Tún Gba Òfin
(Eks 34:1-10)
1NIGBANA li OLUWA wi fun mi pe, Gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju, ki o si tọ̀ mi wá lori òke na, ki o si ṣe apoti igi kan.
2Emi o si kọ ọ̀rọ ti o ti wà lara walã iṣaju ti iwọ fọ́, sara walã wọnyi, iwọ o si fi wọn sinu apoti na.
3Emi si ṣe apoti igi ṣittimu kan, mo si gbẹ́ walã okuta meji bi ti isaju, mo si lọ sori òke na, walã mejeji si wà li ọwọ́ mi.
4On si kọ ofin mẹwẹwa sara walã wọnni, gẹgẹ bi o ti kọ ti iṣaju, ti OLUWA sọ fun nyin lori òke na lati inu ãrin iná wá li ọjọ́ ajọ nì; OLUWA si fi wọn fun mi.
5Mo si pada, mo si sọkalẹ lati ori òke na wá, mo si fi walã wọnni sinu apoti ti mo ti ṣe; nwọn si wà nibẹ̀, bi OLUWA ti paṣẹ fun mi.
6(Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati Beerotu ti iṣe ti awọn ọmọ Jaakani lọ si Mosera: nibẹ̀ li Aaroni gbé kú, nibẹ̀ li a si sin i; Eleasari ọmọ rẹ̀ si nṣe iṣẹ alufa ni ipò rẹ̀.
7Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Gudgoda; ati lati Gudgoda lọ si Jotbati, ilẹ olodò omi.
8Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.
9Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.)
10Emi si duro lori òke na, gẹgẹ bi ìgba iṣaju, li ogoji ọsán ati ogoji oru: OLUWA si gbọ́ ti emi ni igbana pẹlu, OLUWA kò si fẹ́ run ọ.
11OLUWA si wi fun mi pe, Dide, mú ọ̀na ìrin rẹ niwaju awọn enia, ki nwọn ki o le wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki nwọn ki o le gbà ilẹ na, ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.
Ohun Tí Ọlọrun Ń Bèèrè
12Njẹ nisisiyi, Israeli, kini OLUWA Ọlọrun rẹ mbère lọdọ rẹ, bikoṣe lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, lati ma fẹ́ ẹ, ati lati ma sìn OLUWA Ọlọrun rẹ pẹlu àiya rẹ gbogbo, ati pẹlu ọkàn rẹ gbogbo,
13Lati ma pa ofin OLUWA mọ́, ati ìlana rẹ̀, ti mo filelẹ fun ọ li aṣẹ li oni, fun ire rẹ?
14Kiyesi i, ti OLUWA Ọlọrun rẹ li ọrun, ati ọrun dé ọrun, aiye pẹlu, ti on ti ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.
15Kìki OLUWA ni inudidùn si awọn baba rẹ lati fẹ́ wọn, on si yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, ani ẹnyin jù gbogbo enia lọ, bi o ti ri li oni yi.
16Nitorina ẹ kọ àiya nyin nilà, ki ẹ má si ṣe ọlọrùn lile mọ́.
17Nitori OLUWA Ọlọrun nyin, Ọlọrun awọn ọlọrun ni ati OLUWA awọn oluwa, Ọlọrun titobi, alagbara, ati ẹ̀lẹru, ti ki iṣe ojuṣaju, bẹ̃ni ki igba abẹtẹlẹ.
18On ni ima ṣe idajọ alainibaba ati opó, o si fẹ́ alejò, lati fun u li onjẹ ati aṣọ.
19Nitorina ki ẹnyin ki o ma fẹ́ alejò: nitoripe ẹnyin ṣe alejò ni ilẹ Egipti.
20Ki iwọ ki o ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ; on ni ki iwọ ki o ma sìn, on ni ki iwọ ki o si faramọ́, orukọ rẹ̀ ni ki o si ma fi bura.
21On ni iyìn rẹ, on si li Ọlọrun rẹ, ti o ṣe ohun nla ati ohun ẹ̀lẹru wọnni fun ọ, ti oju rẹ ri.
22Awọn baba rẹ sọkalẹ lọ si Egipti ti awọn ti ãdọrin enia; ṣugbọn nisisiyi OLUWA Ọlọrun rẹ sọ ọ dabi irawọ ọrun li ọ̀pọlọpọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 10: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.