Deu 28
28
Ibukun fún Ìgbọràn
(Lef 26:3-13; Deu 7:12-24)
1YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ:
2Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ.
3Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko.
4Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.
5Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ.
6Ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, ibukún ni fun ọ nigbati iwọ ba jade.
7OLUWA yio mu awọn ọtá rẹ ti o dide si ọ di ẹni ikọlù niwaju rẹ: nwọn o jade si ọ li ọ̀na kan, nwọn o si sá niwaju rẹ li ọ̀na meje.
8OLUWA yio paṣẹ ibukún sori rẹ ninu aká rẹ, ati ninu ohun gbogbo ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé; on o si busi i fun ọ ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
9OLUWA yio fi idi rẹ kalẹ li enia mimọ́ fun ara rẹ̀, bi o ti bura fun ọ, bi iwọ ba pa aṣẹ ỌLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, ti iwọ si rìn li ọ̀na rẹ̀.
10Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ.
11OLUWA yio si sọ ọ di pupọ̀ fun rere, ninu ọmọ inu rẹ, ati ninu irú ohunọ̀sin rẹ, ati ninu eso ilẹ rẹ, ni ilẹ ti OLUWA ti bura fun awọn baba rẹ lati fun ọ.
12OLUWA yio ṣí iṣura rere rẹ̀ silẹ fun ọ, ọrun lati rọ̀jo si ilẹ rẹ li akokò rẹ̀, ati lati busi iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: iwọ o si ma wín orilẹ-ède pupọ̀, iwọ ki yio si tọrọ.
13OLUWA yio si fi ọ ṣe ori, ki yio si ṣe ìru; iwọ o si ma leke ṣá, iwọ ki yio si jẹ́ ẹni ẹhin; bi o ba fetisi aṣẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ti mo pa fun ọ li oni, lati ma kiyesi on ati ma ṣe wọn;
14Iwọ kò si gbọdọ yà kuro ninu gbogbo ọ̀rọ ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, si ọtún, tabi si òsi, lati tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn.
Ìjìyà fún Àìgbọràn
(Lef 26:14-46)
15Yio si ṣe, bi iwọ kò ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ ti mo filelẹ fun ọ li oni; njẹ gbogbo egún wọnyi yio ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ.
16Egún ni fun ọ ni ilu, egún ni fun ọ li oko.
17Egún ni fun agbọ̀n rẹ ati ọpọ́n-ipò-àkara rẹ.
18Egún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.
19Egún ni fun ọ nigbati iwọ ba wọle, egún si ni fun ọ nigbati iwọ ba jade.
20OLUWA yio si rán egún, idamu, ati ibawi sori rẹ, ninu gbogbo ohun ti iwọ ba fi ọwọ́ rẹ lé ni ṣiṣe, titi a o fi run ọ, ati titi iwọ o fi ṣegbé kánkán; nitori buburu iṣe rẹ, nipa eyiti iwọ fi kọ̀ mi silẹ.
21OLUWA yio si mu ajakalẹ-àrun lẹ̀ mọ́ ọ, titi on o fi run ọ kuro lori ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.
22OLUWA yio si fi àrun-igbẹ kọlù ọ, ati ibà, ati igbona, ati ijoni nla, ati idà, ati ìrẹdanu, ati imuwodu; nwọn o si lepa rẹ titi iwọ o fi run.
23Ọrun rẹ ti mbẹ lori rẹ yio jẹ́ idẹ, ilẹ ti mbẹ nisalẹ rẹ yio si jẹ́ irin.
24OLUWA yio sọ òjo ilẹ rẹ di ẹ̀tù ati ekuru: lati ọrun ni yio ti ma sọkalẹ si ọ, titi iwọ o fi run.
25OLUWA yio si mu ọ di ẹni ikọlù niwaju awọn ọtá rẹ: iwọ o jade tọ̀ wọn lọ li ọ̀na kan, iwọ o si sá niwaju wọn li ọ̀na meje: a o si ṣí ọ kiri gbogbo ijọba aiye.
26Okú rẹ yio si jẹ́ onjẹ fun gbogbo ẹiyẹ oju-ọ̀run, ati fun ẹranko aiye, kò si sí ẹniti yio lé wọn kuro.
27OLUWA yio si fi õwo Egipti lù ọ, ati iyọdi, ati ekúru, ati ẹyi-ara, eyiti a ki yio le wòsan.
28OLUWA yio fi isinwin kọlù ọ, ati ifọju, ati ipàiya:
29Iwọ o si ma fi ọwọ́ talẹ li ọsán gangan, bi afọju ti ifi ọwọ́ talẹ ninu òkunkun, iwọ ki yio si ri rere ninu ọ̀na rẹ: ẹni inilara ṣá ati ẹni kikó li ọjọ́ gbogbo ni iwọ o jẹ́, ki o si sí ẹniti o gbà ọ.
30Iwọ o fẹ́ iyawo, ọkunrin miran ni yio si bá a dàpọ: iwọ o kọ ile, iwọ ki yio si gbé inu rẹ̀: iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ ki yio si ká eso rẹ̀.
31A o si pa akọmalu rẹ li oju rẹ, iwọ ki yio si jẹ ninu rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ rẹ li a o si fi agbara mú lọ kuro li oju rẹ, a ki yio si mú u pada fun ọ wá: a o fi agutan rẹ fun awọn ọtá rẹ, iwọ ki yio si lí ẹniti yio gbà ọ.
32Awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, li a o fi fun enia miran, oju rẹ yio ma wò, yio si su ọ lati ma wò ọ̀na wọn li ọjọ́ gbogbo: ki yio si sí agbara kan li ọwọ́ rẹ.
33Eso ilẹ rẹ, ati gbogbo iṣẹ-lãlã rẹ, ni orilẹ-ède miran ti iwọ kò mọ̀ yio jẹ; iwọ o si jẹ́ kìki ẹni inilara ati ẹni itẹmọlẹ nigbagbogbo:
34Bẹ̃ni iwọ o si di aṣiwere nitori iran oju rẹ, ti iwọ o ri.
35OLUWA yio si fi õwo buburu lù ọ li ẽkún, ati li ẹsẹ̀, ti a ki o le wòsan, lati atẹlẹsẹ̀ rẹ dé atari rẹ.
36OLUWA o mú iwọ, ati ọba rẹ ti iwọ o fi jẹ́ lori rẹ, lọ si orilẹ-ède ti iwọ, ati awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; iwọ o si ma bọ oriṣa nibẹ̀, igi ati okuta.
37Iwọ o si di ẹni iyanu, ati ẹni owe, ati ẹni ifisọrọsọ, ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio gbé darí rẹ si.
38Iwọ o mú irugbìn pupọ̀ lọ sinu oko, diẹ ni iwọ o si ri kójọ; nitoripe eṣú ni yio jẹ ẹ run.
39Iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ o si ṣe itọju rẹ̀, ṣugbọn iwọ ki yio mu ninu ọti-waini rẹ̀, bẹ̃ni iwọ ki yio ká ninu eso-àjara rẹ̀, nitoripe kòkoro ni yio fi wọn jẹ.
40Iwọ o ní igi olifi ni gbogbo àgbegbe rẹ, ṣugbọn iwọ ki yio fi oróro para; nitoripe igi olifi rẹ yio rẹ̀danu.
41Iwọ o bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn nwọn ki yio jẹ́ tirẹ; nitoripe nwọn o lọ si oko-ẹrú.
42Gbogbo igi rẹ ati eso ilẹ rẹ yio jẹ́ ti eṣú.
43Alejò ti mbẹ lãrin rẹ, yio ma ga jù ọ lọ siwaju ati siwaju, iwọ o si ma di ẹni irẹsilẹ, siwaju ati siwaju.
44On ni yio ma wín ọ, iwọ ki yio si wín i: on ni yio ma ṣe ori, iwọ o si ma ṣe ìru.
45Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ.
46Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai:
47Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo:
48Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.
49OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀;
50Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe:
51On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ.
52On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ.
53Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́.
54Ọkunrin ti àwọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, oju rẹ̀ yio korò si arakunrin rẹ̀, ati si aya õkanàiya rẹ̀, ati si iyokù ọmọ rẹ̀ ti on jẹ kù:
55Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo.
56Obinrin ti awọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti kò jẹ daṣa ati fi atẹlẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ nitori ikẹra ati ìwa-ẹlẹgẹ́, oju rẹ̀ yio korò si ọkọ õkanaiya rẹ̀, ati si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin;
57Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ.
58Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ;
59Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ.
60On o si mú gbogbo àrun Egipti pada wá bá ọ, ti iwọ bẹ̀ru; nwọn o si lẹ̀ mọ́ ọ.
61Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run.
62Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́.
63Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a.
64OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta.
65Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ:
66Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ.
67Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri.
68OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 28: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.