Deu 8
8
Ilẹ̀ Tí Ó Dára fún Ìní
1GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin.
2Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ.
3O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye.
4Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá.
5Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi.
6Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀.
7Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa;
8Ilẹ alikama ati ọkà-barle, ati àjara ati igi ọpọtọ ati igi pomegranate; ilẹ oróro olifi, ati oyin;
9Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ.
10Nigbati iwọ ba si jẹun tán ti o si yo, nigbana ni iwọ o fi ibukún fun OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori ilẹ rere na ti o fi fun ọ.
Ìkìlọ̀ nípa Gbígbàgbé OLUWA
11Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ṣe gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, li aipa ofin rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni:
12Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀;
13Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i;
14Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú;
15Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá;
16Ẹniti o fi manna bọ́ ọ li aginjù, ti awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; ki o le rẹ̀ ọ silẹ, ki o le dan ọ wò, lati ṣe ọ li ore nigbẹhin rẹ:
17Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ́ mi li o fun mi li ọrọ̀ yi.
18Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ̀, ki on ki o le fi idi majẹmu rẹ̀ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi.
19Yio si ṣe, bi iwọ ba gbagbe OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ si tẹle ọlọrun miran, ti o si nsìn wọn, ti o si mbọ wọn, emi tẹnumọ́ ọ fun nyin pe, rirun li ẹnyin o run.
20Bi awọn orilẹ-ède ti OLUWA run kuro niwaju nyin, bẹ̃li ẹnyin o run; nitoripe ẹnyin ṣe àigbọran si ohùn OLUWA Ọlọrun nyin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Deu 8: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.