Oni 11
11
1FUN onjẹ rẹ si oju omi; nitoriti iwọ o ri i lẹhin ọjọ pupọ.
2Fi ipin fun meje ati fun mẹjọ pẹlu, nitoriti iwọ kò mọ̀ ibi ti yio wà laiye.
3Bi awọsanma ba kún fun òjo, nwọn a si tu dà si aiye: bi igi ba si wó sìha gusu tabi siha ariwa, nibiti igi na gbe ṣubu si, nibẹ ni yio si ma gbe.
4Ẹniti o nkiyesi afẹfẹ kì yio funrugbin; ati ẹniti o si nwòju awọsanma kì yio ṣe ikore.
5Bi iwọ kò ti mọ ipa-ọ̀na afẹfẹ, tabi bi egungun ti idàgba ninu aboyun: ani bẹ̃ni iwọ kò le mọ̀ iṣẹ Ọlọrun ti nṣe ohun gbogbo.
6Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna.
7Nitõtọ imọlẹ dùn ati ohun didara ni fun oju lati wò õrùn.
8Ṣugbọn bi enia wà li ọ̀pọlọpọ ọdun, ti o si nyọ̀ ninu gbogbo wọn, sibẹ, jẹ ki o ranti ọjọ òkunkun pe nwọn o pọ̀. Ohun gbogbo ti mbọ̀, asan ni.
9Mã yọ̀, iwọ ọdọmọde ninu ewe rẹ; ki o si jẹ ki ọkàn rẹ ki o mu ọ laraya li ọjọ ewe rẹ, ki o si ma rìn nipa ọ̀na ọkàn rẹ ati nipa irí oju rẹ; ṣugbọn iwọ mọ̀ eyi pe, nitori nkan wọnyi Ọlọrun yio mu ọ wá si idajọ.
10Nitorina ṣi ibinujẹ kuro li aiya rẹ, ki o si mu ibi kuro li ara rẹ: nitoripe asan ni igba-ewe ati ọmọde.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Oni 11: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: