Oni 12
12
1RANTI ẹlẹda rẹ nisisiyi li ọjọ ewe rẹ, nigbati ọjọ ibi kò ti ide, ati ti ọdun kò ti isunmọ etile, nigbati iwọ o wipe, emi kò ni inudidùn ninu wọn;
2Nigbati õrùn, tabi imọlẹ, tabi oṣupa tabi awọn irawọ kò ti iṣu òkunkun, ati ti awọsanma kò ti itun pada lẹhin òjo:
3Li ọjọ ti awọn oluṣọ ile yio warìri, ati ti awọn ọkunrin alagbara yio tẹri wọn ba, awọn õlọ̀ yio si dakẹ nitoriti nwọn kò to nkan, ati awọn ti nwode loju ferese yio ṣu òkunkun,
4Ti ilẹkun yio si se ni igboro, nigbati iró ọlọ yio rẹlẹ, ti yio si dide li ohùn kike ẹiyẹ, ati ti gbogbo awọn ọmọbinrin orin yio rẹ̀ silẹ;
5Ati pẹlu ti nwọn o bẹ̀ru ibi ti o ga, ti iwariri yio si wà li ọ̀na, ati ti igi almondi yio tanna, ti ẹlẹnga yio di ẹrù, ti ifẹ yio si ṣá: nitoriti ọkunrin nlọ si ile rẹ̀ pipẹ, awọn aṣọ̀fọ yio si ma yide kakiri.
6Tabi ki okùn fadaka ki o to tu, tabi ki ọpọn wura ki o to fọ, tabi ki ìṣa ki o to fọ nibi isun, tabi ki ayika-kẹkẹ ki o to kán nibi kanga.
7Nigbana ni erupẹ yio pada si ilẹ bi o ti wà ri, ẹmi yio si pada tọ̀ Ọlọrun ti o fi i funni.
8Asan ninu asan, oniwasu wipe, gbogbo rẹ̀ asan ni.
9Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.
10Oniwasu wadi ati ri ọ̀rọ didùn eyiti a si kọ, ohun iduro-ṣinṣin ni, ani ọ̀rọ otitọ.
11Ọ̀rọ ọlọgbọ́n dabi ẹgún, ati awọn olori akojọ-ọ̀rọ bi iṣó ti a kàn, ti a nfi fun ni lati ọwọ oluṣọ-agutan kan wá.
12Ati siwaju, lati inu eyi, ọmọ mi, ki o gbà ìmọran: ninu kikọ iwe pupọ, opin kò si: ati iwe kikà pupọ li ãrẹ̀ ara.
13Opin gbogbo ọ̀rọ na ti a gbọ́ ni pe: Bẹ̀ru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ̀ mọ́: nitori eyi ni fun gbogbo enia.
14Nitoripe Ọlọrun yio mu olukuluku iṣẹ wa sinu idajọ, ati olukuluku ohun ìkọkọ, ibã ṣe rere, ibã ṣe buburu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Oni 12: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: