Efe 4:21-32

Efe 4:21-32 YBCV

Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu: Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan; Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin; Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́. Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe. Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin: Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu. Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini. Ẹ máṣe jẹ ki ọ̀rọ idibajẹ kan ti ẹnu nyin jade, ṣugbọn iru eyiti o dara fun ẹ̀kọ́, ki o le mã fi ore-ọfẹ fun awọn ti ngbọ́. Ẹ má si ṣe mu Ẹmí Mimọ́ Ọlọrun binu, ẹniti a fi ṣe èdidi nyin dè ọjọ idande. Gbogbo ìwa kikorò, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ nyin, pẹlu gbogbo arankàn: Ẹ mã ṣore fun ọmọnikeji nyin, ẹ ni iyọ́nu, ẹ mã darijì ara nyin, gẹgẹ bi Ọlọrun ninu Kristi ti darijì nyin.