Est 1
1
Ayaba Faṣiti Rí Ahaswerusi Ọba Fín
1O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:)
2Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin.
3Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse kan fun gbogbo awọn ijoye ati awọn iranṣẹ rẹ̀; awọn balogun Persia ati Media, awọn ọlọla, ati awọn olori ìgberiko wọnni wà niwaju rẹ̀:
4Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ.
5Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba.
6Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́.
7Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.
8Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku.
9Faṣti ayaba sè àse pẹlu fun gbogbo awọn obinrin ni ile ọba ti iṣe ti Ahaswerusi.
10Li ọjọ keje, nigbati ọti-waini mu inu ọba dùn, o paṣẹ fun Mehumani, Bista, Harbona, Bigta ati Abagta, Ṣetari ati Karkasi, awọn iwẹfa meje ti njiṣẹ niwaju Ahaswerusi ọba.
11Lati mu Faṣti, ayaba wá siwaju ọba, ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia, ati awọn ijoye: nitori arẹwà obinrin ni.
12Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si gbiná ninu rẹ̀.
13Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ:
14Awọn ti o sunmọ ọ ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye Persia ati Media mejeje, ti nri oju ọba, ti nwọn si joko ni ipò ikini ni ijọba).
15Pe, gẹgẹ bi ofin, Kini ki a ṣe si Faṣti ayaba, nitoriti on kò ṣe bi Ahaswerusi ọba ti paṣẹ fun u, lati ọwọ awọn ìwẹfa rẹ̀ wá?
16Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikan, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye, ati si gbogbo awọn enia ti o wà ni ìgberiko Ahaswerusi ọba.
17Nitori ìwa ayaba yi yio tàn de ọdọ gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio di gigàn loju wọn, nigbati a o sọ ọ wi pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe, ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá.
18Awọn ọlọla-obinrin Persia ati Media yio si ma wi bakanna li oni yi fun gbogbo awọn ijoye ọba ti nwọn gbọ́ ìwa ti ayaba hù. Bayi ni ẹ̀gan pipọ̀-pipọ̀, ati ibinu yio dide.
19Bi o ba dara loju ọba, ki aṣẹ ọba ki o ti ọdọ rẹ̀ lọ, ki a si kọ ọ pẹlu awọn ofin Persia ati Media, ki a má ṣe le pa a dà, pe, ki Faṣti ki o máṣe wá siwaju Ahaswerusi ọba mọ, ki ọba ki o si fi oyè ayaba rẹ̀ fun ẹgbẹ rẹ̀ ti o san jù u lọ.
20Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa yi gbogbo ijọba rẹ̀ ka, (nitori on sa pọ̀) nigbana ni gbogbo awọn obinrin yio ma bọ̀wọ fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe.
21Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani:
22Nitori on ran ìwe si gbogbo ìgberiko ọba, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède rẹ̀, ki olukulùku ọkunrin ki o le ṣe olori ni ile tirẹ̀, ati ki a le kede rẹ̀ gẹgẹ bi ède enia rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Est 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.