Eks 18
18
1NIGBATI Jetro, alufa Midiani, ana Mose, gbọ́ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun Mose, ati fun Israeli awọn enia rẹ̀, ati pe, OLUWA mú Israeli lati Egipti jade wá;
2Nigbana ni Jetro, ana Mose, mú Sippora aya Mose wá, lẹhin ti o ti rán a pada.
3Ati awọn ọmọ rẹ̀ mejeji: ti orukọ ọkan njẹ Gerṣomu; nitoriti o wipe, Emi ṣe alejò ni ilẹ ajeji.
4Ati orukọ ekeji ni Elieseri; nitoriti o wipe, Ọlọrun baba mi li alatilẹhin mi, o si gbà mi lọwọ idà Farao:
5Ati Jetro, ana Mose, o tọ̀ Mose wá ti on ti awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀ si ijù, nibiti o gbé dó si lẹba oke Ọlọrun.
6O si wi fun Mose pe, Emi Jetro ana rẹ li o tọ̀ ọ wá, pẹlu aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ̀.
7Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́.
8Mose si sọ ohun gbogbo ti OLUWA ti ṣe si Farao, ati si awọn ara Egipti nitori Israeli fun ana rẹ̀, ati gbogbo ipọnju ti o bá wọn li ọ̀na, ati bi OLUWA ti gbà wọn.
9Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti.
10Jetro si wipe, Olubukún li OLUWA, ẹniti o gbà nyin là lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ Farao, ẹniti o gbà awọn enia là lọwọ awọn ara Egipti.
11Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn.
12Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun.
13O si ṣe ni ijọ́ keji ni Mose joko lati ma ṣe idajọ awọn enia: awọn enia si duro tì Mose lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.
14Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ?
15Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni:
16Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀.
17Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara.
18Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ.
19Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun.
20Ki o si ma kọ́ wọn ni ìlana ati ofin wọnni, ki o si ma fi ọ̀na ti nwọn o ma rìn hàn fun wọn ati iṣẹ ti nwọn o ma ṣe.
21Pẹlupẹlu iwọ o si ṣà ninu gbogbo awọn enia yi awọn ọkunrin ti o to, ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awọn ọkunrin olõtọ, ti o korira ojukokoro; irú awọn wọnni ni ki o fi jẹ́ olori wọn, lati ṣe olori ẹgbẹgbẹrun, ati olori ọrọrún, ati olori arãdọta, ati olori mẹwamẹwa.
22Ki nwọn ki o si ma ṣe idajọ awọn enia nigbakugba: yio si ṣe, gbogbo ẹjọ́ nla ni ki nwọn ki o ma mú tọ̀ ọ wá, ṣugbọn gbogbo ẹjọ́ kekeké ni ki nwọn ki o ma dá: yio si rọrùn fun iwọ tikalarẹ, nwọn o si ma bá ọ rù ẹrù na.
23Bi iwọ ba jẹ ṣe nkan yi, bi Ọlọrun ba si fi aṣẹ fun ọ bẹ̃, njẹ iwọ o le duro pẹ, ati gbogbo awọn enia yi pẹlu ni yio si dé ipò wọn li alafia.
24Mose si gbà ohùn ana rẹ̀ gbọ́, o si ṣe ohun gbogbo ti o wi.
25Mose si yàn awọn enia ti o to ninu gbogbo Israeli, o si fi wọn ṣe olori awọn enia, olori ẹgbẹgbẹrun, olori ọrọrún, olori arãdọta, olori mẹwamẹwa.
26Nwọn si nṣe idajọ awọn enia nigbakugba: ọ̀ran ti o ṣoro, nwọn a mútọ̀ Mose wá, ṣugbọn awọn tikalawọn ṣe idajọ gbogbo ọ̀ran kekeké.
27Mose si jẹ ki ana rẹ̀ ki o lọ; on si ba tirẹ̀ lọ si ilẹ rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.