Eks 29
29
1EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku.
2Ati àkara alaiwu, ati adidùn àkara alaiwu ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si lori; iyẹfun alikama ni ki o fi ṣe wọn.
3Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji.
4Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn.
5Iwọ o si mú aṣọ wọnni, iwọ o si fi ẹ̀wu-awọtẹlẹ nì wọ̀ Aaroni, ati aṣọ igunwa efodi, ati efodi, ati igbàiya, ki o si fi onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi dì i.
6Iwọ o si fi fila nì dé e li ori, iwọ o si fi adé mimọ́ nì sara fila na.
7Nigbana ni iwọ o si mú oróro itasori, iwọ o si dà a si i li ori, iwọ o si fi oróro yà a simimọ́.
8Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá tosi, iwọ o si wọ̀ wọn li ẹ̀wu.
9Iwọ o si dì wọn li ọjá-amure, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si fi fila dé wọn: iṣẹ-alufa yio si ma jẹ́ ti wọn ni ìlana titi aiye: iwọ o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́.
10Iwọ o si mú akọmalu na wá siwaju agọ́ ajọ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé akọmalu na li ori.
11Iwọ o si pa akọmalu na niwaju OLUWA, loju ọ̀na agọ́ ajọ.
12Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na.
13Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na.
14Ṣugbọn ẹran akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati igbẹ rẹ̀, on ni ki iwọ ki o fi iná sun lẹhin ode ibudó: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
15Iwọ o si mú àgbo kan; ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori.
16Iwọ o si pa àgbo na, iwọ o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀, iwọ o si fi i wọ́n pẹpẹ na yiká.
17Iwọ o si kun àgbo na, iwọ o si fọ̀ ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀, iwọ o si fi wọn lé ara wọn, ati lé ori rẹ̀.
18Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
19Iwọ o si mú àgbo keji; Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori.
20Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká.
21Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
22Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni:
23Ati ìṣu àkara kan, ati àkara kan ti a fi oróro din, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan kuro ninu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA:
24Iwọ o si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni lọwọ, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀; iwọ o si ma fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.
25Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
26Iwọ o si mú igẹ̀ àgbo ìyasimimọ́ Aaroni, iwọ o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; ìpín tirẹ li eyinì.
27Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀:
28Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA.
29Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn.
30Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì.
31Iwọ o si mú àgbo ìyasimimọ́ nì, iwọ o si bọ̀ ẹran rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan.
32Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si jẹ ẹran àgbo na, ati àkara na ti o wà ninu agbọ̀n nì, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
33Nwọn o si jẹ nkan wọnni ti a fi ṣètutu na, lati yà wọn simimọ́, ati lati sọ wọn di mimọ́: ṣugbọn alejò ni kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, nitoripe mimọ́ ni.
34Bi ohun kan ninu ẹran ìyasimimọ́ na, tabi ninu àkara na, ba kú titi di ojumọ́, nigbana ni ki iwọ ki o fi iná sun iyokù: a ki yio jẹ ẹ, nitoripe mimọ́ ni.
35Bayi ni iwọ o si ṣe fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti mo paṣẹ fun ọ: ijọ́ meje ni iwọ o fi yà wọn simimọ́.
36Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́.
37Ni ijọ́ meje ni iwọ o fi ṣètutu si pẹpẹ na, iwọ o si yà a simimọ́: on o si ṣe pẹpẹ mimọ́ julọ; ohunkohun ti o ba fọwọkàn pẹpẹ na, mimọ́ ni yio jẹ́.
38Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai.
39Ọdọ-agutan kan ni iwọ o fi rubọ li owurọ̀; ati ọdọ-agutan keji ni iwọ o fi rubọ li aṣalẹ:
40Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini.
41Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
42Ẹbọ sisun titilai ni yio ṣe lati irandiran nyin li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA: nibiti emi o ma bá nyin pade lati ma bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀.
43Nibẹ̀ li emi o ma pade awọn ọmọ Israeli; a o si fi ogo mi yà agọ́ na simimọ́.
44Emi o si yà agọ́ ajọ na simimọ́, ati pẹpẹ nì: emi o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́, lati ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
45Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.
46Nwọn o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun wọn, ti o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá, ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn: emi li OLUWA Ọlọrun wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 29: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.