Eks 31
31
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah:
3Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà.
4Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ,
5Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.
6Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:
7Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na.
8Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari;
9Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀;
10Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa;
11Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe.
12OLUWA si sọ fun Mose pe,
13Ki iwọ ki o sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ isimi mi li ẹnyin o pamọ́ nitõtọ: nitori àmi ni lãrin emi ati lãrin nyin lati irandiran nyin; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA ti o yà nyin simimọ́.
14Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
15Ijọ́ mẹfa ni ki a ṣe iṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ́ keje ni ọjọ́ isimi, mimọ́ ni si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ li ọjọ́ isimi, on li a o si pa nitõtọ.
16Nitorina li awọn ọmọ Israeli yio ṣe ma pa ọjọ́ isimi mọ́, lati ma kiyesi ọjọ́ isimi lati irandiran wọn, fun majẹmu titilai.
17Àmi ni iṣe lãrin emi ati lãrin awọn ọmọ Israeli titilai: nitori ni ijọ́ mẹfa li OLUWA dá ọrun on aiye, ni ijọ́ keje o si simi, o si ṣe ìtura.
18O si fi walã ẹrí meji, walã okuta, ti a fi ika Ọlọrun kọ, fun Mose, nigbati o pari ọ̀rọ bibá a sọ tán lori oke Sinai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Eks 31: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.