Esek Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ní nǹkan bíi ẹgbẹta ọdún ó dín mẹrinla kí á tó bí OLUWA wa (586 B.C.), ni ogun kó Jerusalẹmu. Wolii Esekiẹli wà ní ìgbèkùn ní Babiloni ní ọdún bíi mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, ati lẹ́yìn rẹ̀. Ìpín mẹfa pataki ni ó wà ninu Ìwé Esekiẹli: (1) Ìpè Esekiẹli sí iṣẹ́ wolii. (2) Àwọn ìkìlọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn eniyan náà ati nípa ìṣubú ati ìparun Jerusalẹmu. (3) Ìdájọ́ OLUWA lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ni àwọn eniyan OLUWA lára, ati àwọn tí wọ́n ṣì wọ́n lọ́nà. (4) Lẹ́yìn tí ogun kó Jerusalẹmu, OLUWA ranṣẹ ìtùnú sí àwọn eniyan rẹ̀ ó sì ṣèlérí pé ọjọ́ iwájú yóo dára. (5) Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu. (6) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili tí wọn yóo tún kọ́ yóo ti rí, ati pé ó gbọdọ̀ wà ní mímọ́.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọlọrun pe Esekiẹli 1:1—3:27
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun tí yóo dé bá Jerusalẹmu 4:1—24:27
Ìdájọ́ Ọlọrun lórí àwọn orílẹ̀-èdè 25:1—32:32
Ìlérí Ọlọrun nípa àwọn eniyan rẹ̀ 33:1—37:28
Àsọtẹ́lẹ̀ ibi nípa Gogu 38:1—39:29
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Tẹmpili ati ilẹ̀ náà ní ọjọ́ iwájú yóo ti rí 40:1—48:35

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Esek Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀