Gẹn 12:1-9

Gẹn 12:1-9 YBCV

OLUWA si ti wi fun Abramu pe, Jade kuro ni ilẹ rẹ, ati kuro lọdọ awọn ara rẹ, ati kuro ni ile baba rẹ, si ilẹ kan ti emi o fi hàn ọ: Emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla, emi o si busi i fun ọ, emi o si sọ orukọ rẹ di nla; ibukun ni iwọ o si jasi: Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré; ninu rẹ li a o ti bukun fun gbogbo idile aiye. Bẹ̃li Abramu lọ, bi OLUWA ti sọ fun u; Loti si ba a lọ: Abramu si jẹ ẹni arundilọgọrin ọdún nigbati o jade ni Harani. Abramu si mu Sarai aya rẹ̀, ati Loti ọmọ arakunrin rẹ̀, ati gbogbo ini wọn ti nwọn kojọ, enia gbogbo ti nwọn ni ni Harani, nwọn si jade lati lọ si ilẹ Kenaani; ni ilẹ Kenaani ni nwọn si wá si. Abramu si là ilẹ na kọja lọ si ibi ti a npè ni Ṣekemu, si igbo More. Awọn ara Kenaani si wà ni ilẹ na ni ìgba na. OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a. O si ṣí kuro nibẹ̀ lọ si ori oke kan ni ìha ìla-õrùn Beteli, o si pa agọ́ rẹ̀, Beteli ni ìwọ-õrùn ati Hai ni ìla-õrùn: o si tẹ́ pẹpẹ kan nibẹ̀ fun OLUWA, o si kepè orukọ OLUWA. Abramu si nrìn lọ, o nlọ si ìha gusù sibẹ̀.