Gẹn 37

37
Josẹfu ati Àwọn Arakunrin Rẹ̀
1JAKOBU si joko ni ilẹ ti baba rẹ̀ ti ṣe atipo, ani ilẹ Kenaani.
2Wọnyi ni iran Jakobu. Nigbati Josefu di ẹni ọdún mẹtadilogun, o nṣọ́ agbo-ẹran pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; ọmọde na si wà pẹlu awọn ọmọ Bilha, ati pẹlu awọn ọmọ Silpa, awọn aya baba rẹ̀; Josefu si mú ihin buburu wọn wá irò fun baba wọn.
3Israeli si fẹ́ Josefu jù gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ lọ, nitori ti iṣe ọmọ ogbó rẹ̀; o si dá ẹ̀wu alarabara aṣọ fun u.
4Nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ri pe baba wọn fẹ́ ẹ jù gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn korira rẹ̀, nwọn kò si le sọ̀rọ si i li alafia.
5Josefu si lá alá kan, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀; nwọn si tun korira rẹ̀ si i.
6O si wi fun wọn pe, Mo bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ alá yi ti mo lá.
7Sa wò o, awa nyí ití li oko, si wò o, ití mi dide, o si duro ṣanṣan; si wò o, ití ti nyin dide duro yiká, nwọn si ntẹriba fun ití mi.
8Awọn arakunrin rẹ̀ si wi fun u pe, Iwọ o ha jọba lori wa bi? tabi iwọ o ṣe olori wa nitõtọ? nwọn si tun korira rẹ̀ si i nitori alá rẹ̀ ati nitori ọ̀rọ rẹ̀.
9O si tun lá alá miran, o si rọ́ ọ fun awọn arakunrin rẹ̀, o wipe, Sa wò o, mo tun lá alá kan si i; si wò o, õrùn, ati oṣupa, ati irawọ mọkanla nforibalẹ fun mi.
10O si rọ́ ọ fun baba rẹ̀, ati fun awọn arakunrin rẹ̀: baba rẹ̀ si bá a wi, o si wi fun u pe, Alá kili eyi ti iwọ lá yi? emi ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ yio ha wá nitõtọ, lati foribalẹ fun ọ bi?
11Awọn arakunrin rẹ̀ si ṣe ilara rẹ̀; ṣugbọn baba rẹ̀ pa ọ̀rọ na mọ́.
Wọ́n Ta Josẹfu Lẹ́rú sí Ijipti
12Awọn arakunrin rẹ̀ si lọ lati bọ́ agbo-ẹran baba wọn ni Ṣekemu.
13Israeli si wi fun Josefu pe, Ni Ṣekemu ki awọn arakunrin rẹ gbé mbọ́ ẹran? wá, emi o si rán ọ si wọn. On si wi fun u pe, Emi niyi.
14O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu.
15Ọkunrin kan si ri i, si wò o, o nrìn kakiri ni pápa: ọkunrin na si bi i pe, Kini iwọ nwá?
16On si wipe, Emi nwá awọn arakunrin mi: mo bẹ̀ ọ, sọ ibi ti nwọn gbé mbọ́ agbo-ẹran wọn fun mi.
17Ọkunrin na si wipe, Nwọn ti lọ kuro nihin; nitori mo gbọ́, nwọn nwipe, ẹ jẹ ki a lọ si Dotani. Josefu si lepa awọn arakunrin rẹ̀, o si ri wọn ni Dotani.
18Nigbati nwọn si ri i lokere; ki o tilẹ to sunmọ eti ọdọ wọn, nwọn di rikiṣi si i lati pa a.
19Nwọn si wi fun ara wọn pe, Wò o, alála nì mbọ̀wá.
20Nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a pa a, ki a si wọ́ ọ sọ sinu ọkan ninu ihò wọnyi, awa o si wipe ẹranko buburu li o pa a jẹ: awa o si ma wò bi alá rẹ̀ yio ti ri.
21Reubeni si gbọ́, o si gbà a li ọwọ́ won; o si wipe, Ẹ máṣe jẹ ki a gbà ẹmi rẹ̀.
22Reubeni si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe ta ẹ̀jẹ, ṣugbọn ẹ sọ ọ sinu ihò yi ti mbẹ li aginjù, ki ẹ má si fọwọkàn a; nitori ki o ba le gbà a lọwọ wọn lati mú u pada tọ̀ baba rẹ̀ lọ.
23O si ṣe nigbati Josefu dé ọdọ awọn arakunrin rẹ̀, nwọn bọ́ ẹ̀wu Josefu, ẹ̀wu alarabara aṣọ ti o wà lara rẹ̀;
24Nwọn si mú u, nwọn si gbe e sọ sinu ihò kan: ihò na si gbẹ, kò li omi.
25Nwọn si joko lati jẹun: nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn si wò, si kiyesi i, ọwọ́-èro ara Iṣmaeli nti Gileadi bọ̀; ti awọn ti ibakasiẹ ti o rù turari ati ikunra ati ojia, nwọn nmú wọn lọ si Egipti.
26Judah si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Ere ki li o jẹ́ bi awa ba pa arakunrin wa, ti a si bò ẹ̀jẹ rẹ̀?
27Ẹ wá ẹ jẹ ki a tà a fun awọn ara Iṣmaeli ki a má si fọwọ wa kàn a; nitori arakunrin wa ati ara wa ni iṣe. Awọn arakunrin rẹ̀ si gbà tirẹ̀.
28Nigbana li awọn oniṣòwo ara Midiani nkọja lọ; nwọn si fà a, nwọn si yọ Josefu jade ninu ihò, nwọn si tà Josefu li ogún owo fadaka: nwọn si mú Josefu lọ si Egipti.
29Reubeni si pada lọ si ihò; si wò o, Josefu kò sí ninu ihò na; o si fà aṣọ rẹ̀ ya.
30O si pada tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wipe, Ọmọde na kò sí; ati emi, nibo li emi o gbé wọ̀?
31Nwọn si mú ẹ̀wu Josefu, nwọn si pa ọmọ ewurẹ kan, nwọn si rì ẹ̀wu na sinu ẹ̀jẹ na.
32Nwọn si fi ẹ̀wu alarabara aṣọ na ranṣẹ, nwọn si mú u tọ̀ baba wọn wá; nwọn si wipe, Eyi li awa ri: mọ̀ nisisiyi bi ẹ̀wu ọmọ rẹ ni, bi on kọ́.
33On si mọ̀ ọ, o si wipe, Ẹ̀wu ọmọ mi ni; ẹranko buburu ti pa a jẹ; li aiṣe aniani, a ti fà Josefu ya pẹrẹpẹrẹ.
34Jakobu si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ ọ̀fọ si ara rẹ̀, o si ṣọ̀fọ ọmọ rẹ̀ li ọjọ́ pupọ̀.
35Ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ obinrin dide lati ṣìpẹ fun u; ṣugbọn o kọ̀ lati gbipẹ̀; o si wipe, Ninu ọ̀fọ li emi o sa sọkalẹ tọ̀ ọmọ mi lọ si isà-okú. Bayi ni baba rẹ̀ sọkun rẹ̀.
36Awọn ara Midiani si tà a si Egipti fun Potifari, ijoye Farao kan, ati olori ẹṣọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 37: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀