Gẹn 44
44
Ife Tí Ó Sọnù
1O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀.
2Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ.
3Bi ojúmọ si ti mọ́, a si rán awọn ọkunrin na lọ, awọn ati awọn kẹtẹkẹtẹ wọn.
4Nigbati nwọn si jade kuro ni ilu na, ti nwọn kò si jìna, Josefu wi fun iriju rẹ̀ pe, Dide, lepa awọn ọkunrin na; nigbati iwọ ba si bá wọn, wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi fi buburu san rere?
5Ninu eyi ki oluwa mi ima mu, eyiti o si fi nmọ̀ran? ẹnyin ṣe buburu li eyiti ẹnyin ṣe yi.
6O si lé wọn bá, o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn.
7Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi.
8Kiyesi i, owo ti awa ri li ẹnu àpo wa, awa si tun mú pada fun ọ lati ilẹ Kenaani wá: bawo li awa o ṣe jí fadaka tabi wurà ninu ile oluwa rẹ?
9Lọdọ ẹnikẹni ninu awọn iranṣẹ rẹ ti a ba ri i, ki o kú, ati awa pẹlu ki a di ẹrú oluwa mi.
10O si wipe, Njẹ ki o si ri bẹ̃ gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin: ẹniti a ba ri i li ọwọ́ rẹ̀ on ni yio di ẹrú mi, ẹnyin o si ṣe alailẹṣẹ.
11Nigbana ni olukuluku nwọn yara sọ̀ àpo rẹ̀ kalẹ, olukuluku nwọn si tú àpo rẹ̀.
12O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini.
13Nigbana ni nwọn fà aṣọ wọn ya olukuluku si dì ẹrù lé kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, nwọn si pada lọ si ilu.
14Ati Judah ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si ile Josefu; on sa wà nibẹ̀: nwọn si wolẹ niwaju rẹ̀.
15Josefu si wi fun wọn pe, Iwa kili eyiti ẹnyin hù yi? ẹnyin kò mọ̀ pe irú enia bi emi a ma mọ̀ran nitõtọ?
16Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu.
17On si wipe, Ki a má ri pe emi o ṣe bẹ̃: ṣugbọn ọkunrin na li ọwọ́ ẹniti a ri ago na, on ni yio ṣe ẹrú mi; bi o ṣe ti ẹnyin, ẹ goke tọ̀ baba nyin lọ li alafia.
Juda Bẹ̀bẹ̀ fún Ìdásílẹ̀ Bẹnjamini
18Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri.
19Oluwa mi bère lọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, wipe, Ẹnyin ní baba, tabi arakunrin bi?
20Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ.
21Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Mú u sọkalẹ tọ̀ mi wá, ki emi ki o le fi oju mi kàn a.
22Awa si wi fun oluwa mi pe, Ọdọmọde na kò le fi baba rẹ̀ silẹ: nitoripe bi o ba fi i silẹ, baba rẹ̀ yio kú.
23Iwọ si wi fun awọn iranṣẹ rẹ pe, Ayaṣebi arakunrin nyin abikẹhin ba bá nyin sọkalẹ wá, ẹnyin ki yio ri oju mi mọ́.
24O si ṣe nigbati awa goke tọ̀ baba mi iranṣẹ rẹ lọ, awa sọ̀rọ oluwa mi fun u.
25Baba wa si wipe, Ẹ tun lọ irà onjẹ diẹ fun wa wá.
26Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa.
27Baba mi iranṣẹ rẹ si wi fun wa pe Ẹnyin mọ̀ pe aya mi bí ọmọ meji fun mi:
28Ọkan si ti ọdọ mi jade lọ, mo si wipe, Nitõtọ a fà a ya pẹrẹpẹrẹ; emi kò si ri i lati igbana wá:
29Bi ẹnyin ba si mú eyi lọ lọwọ mi pẹlu, ti ibi kan si ṣe e, ibinujẹ li ẹnyin o fi mú ewú mi lọ si isà-okú.
30Njẹ nisisiyi, nigbati mo ba dé ọdọ baba mi, iranṣẹ rẹ, ti ọmọde na kò si wà pẹlu wa; bẹ̃ni ẹmi rẹ̀ dìmọ́ ẹmi ọmọde na;
31Yio si ṣe, bi o ba ri pe ọmọde na kò pẹlu wa, yio kú: awọn iranṣẹ rẹ yio si fi ibinujẹ mú ewú baba wa iranṣẹ rẹ lọ si isà-okú.
32Nitori iranṣẹ rẹ li o ṣe onigbọwọ ọmọde na fun baba mi wipe, Bi emi kò ba mú u tọ̀ ọ wá, emi ni o gbà ẹbi na lọdọ baba mi lailai.
33Njẹ nisisiyi emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o joko ni ipò ọmọde na li ẹrú fun oluwa mi; ki o si jẹ ki ọmọde na ki o bá awọn arakunrin rẹ̀ goke lọ.
34Nitori bi bawo li emi o fi goke tọ̀ baba mi lọ ki ọmọde na ki o ma wà pẹlu mi? ki emi má ba ri ibi ti mbọ̀wá bá baba mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Gẹn 44: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.