Gẹn 49
49
Ọ̀rọ̀ Ìkẹyìn Jakọbu
1JAKOBU si pè awọn ọmọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ kó ara nyin jọ, ki emi ki o le wi ohun ti yio bá nyin lẹhin-ọla fun nyin.
2Ẹ kó ara nyin jọ, ki ẹ si gbọ́, ẹnyin ọmọ Jakobu; ki ẹ si fetisi ti Israeli baba nyin.
3Reubeni, iwọ li akọ́bi mi, agbara mi, ati ipilẹṣẹ ipá mi, titayọ ọlá, ati titayọ agbara.
4Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi.
5Simeoni on Lefi, arakunrin ni nwọn; ohun-èlo ìka ni idà wọn.
6Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì.
7Ifibú ni ibinu wọn, nitori ti o rorò; ati ikannu wọn, nitori ti o ní ìka: emi o pin wọn ni Jakobu, emi o si tú wọn ká ni Israeli.
8Judah, iwọ li ẹniti awọn arakunrin rẹ yio ma yìn; ọwọ́ rẹ yio wà li ọrùn awọn ọtá rẹ; awọn ọmọ baba rẹ yio foribalẹ niwaju rẹ.
9Ọmọ kiniun ni Judah; ọmọ mi, ni ibi-ọdẹ ni iwọ ti goke: o bẹ̀rẹ, o ba bi kiniun, ati bi ogbó kiniun; tani yio lé e dide?
10Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.
11Yio ma so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ ara àjara, ati ọmọ kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ mọ́ ara ãyo àjara; o ti fọ̀ ẹ̀wu rẹ̀ ninu ọtí-waini, ati aṣọ rẹ̀ ninu ẹ̀jẹ eso àjara:
12Oju rẹ̀ yio pọ́n fun ọtí-waini, ehín rẹ̀ yio si funfun fun wàra.
13Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni.
14Issakari ni kẹtẹkẹtẹ ti o lera, ti o dubulẹ lãrin awọn agbo-agutan.
15O si ri pe isimi dara, ati ilẹ na pe o wuni; o si tẹ̀ ejiká rẹ̀ lati rẹrù, on si di ẹni nsìnrú.
16Dani yio ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, bi ọkan ninu awọn ẹ̀ya Israeli.
17Dani yio dabi ejò li ẹba ọ̀na, bi paramọlẹ li ọ̀na, ti ibù ẹṣin ṣán ni gigĩsẹ, tòbẹ̃ ti ẹniti o gùn u yio fi ṣubu sẹhin.
18Emi ti duro dè ìgbala rẹ, OLUWA!
19Gadi ọwọ́-ogun ni yio kọlù u: ṣugbọn on lé wọn.
20Lati inu Aṣeri wá onjẹ rẹ̀ yio lọrá, on o si ma mú adidùn ọba wá.
21Naftali li abo-agbọnrin ti o le sare: o funni li ọ̀rọ rere.
22Josefu li ẹka eleso pupọ̀, ẹka eleso pupọ̀ li ẹba kanga; ẹtun ẹniti o yọ si ori ogiri.
23Awọn tafàtafa bà a ninu jẹ́ pọ̀ju, nwọn si tafà si i, nwọn si korira rẹ̀:
24Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,)
25Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu.
26Ibukún baba rẹ ti jù ibukún awọn baba nla mi lọ, titi dé opin oke aiyeraiye wọnni: nwọn o si ma gbé ori Josefu, ati li atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀.
27Benjamini ni yio ma fàniya bi ikõkò: ni kutukutu ni yio ma jẹ ẹran-ọdẹ rẹ̀, ati li aṣalẹ ni yio ma pín ikogun rẹ̀.
28Gbogbo wọnyi li awọn ẹ̀ya Israeli mejejila: eyi ni baba wọn si sọ fun wọn, o si sure fun wọn; olukuluku bi ibukún tirẹ̀, li o sure fun wọn.
Ikú Jakọbu ati Ìsìnkú Rẹ̀
29O si kìlọ fun wọn, o si sọ fun wọn pe, A o kó mi jọ pọ̀ pẹlu awọn enia mi: ẹ sin mi pẹlu awọn baba mi ni ihò ti o mbẹ li oko Efroni ara Hitti.
30Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku.
31Nibẹ̀ ni nwọn sin Abrahamu ati Sara aya rẹ̀; nibẹ̀ ni nwọn sin Isaaki ati Rebeka aya rẹ̀; nibẹ̀ ni mo si sin Lea:
32Lọwọ awọn ọmọ Heti li a ti rà oko na ti on ti ihò ti o wà nibẹ̀.
33Nigbati Jakobu si ti pari aṣẹ ipa fun awọn ọmọ rẹ̀, o kó ẹsẹ̀ rẹ̀ jọ sori akete, o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, a si kó o jọ pẹlu awọn enia rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Gẹn 49: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.