Gẹn 6

6
Ìwà Burúkú Eniyan
1O si ṣe nigbati enia bẹ̀rẹ si irẹ̀ lori ilẹ, ti a si bí ọmọbinrin fun wọn,
2Ni awọn ọmọ Ọlọrun ri awọn ọmọbinrin enia pe, nwọn lẹwà; nwọn fẹ́ aya fun ara wọn ninu gbogbo awọn ti nwọn yàn.
3OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún.
4Awọn òmirán wà li aiye li ọjọ́ wọnni; ati lẹhin eyini pẹlu, nigbati awọn ọmọ Ọlọrun wọle tọ̀ awọn ọmọbinrin enia lọ, ti nwọn si bí ọmọ fun wọn, awọn na li o di akọni ti o wà nigbãni, awọn ọkunrin olokikí.
5Ọlọrun si ri pe ìwabuburu enia di pipọ̀ li aiye, ati pe gbogbo ìro ọkàn rẹ̀ kìki ibi ni lojojumọ.
6Inu OLUWA si bajẹ nitori ti o dá enia si aiye, o si dùn u de ọkàn rẹ̀.
7OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn.
8Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
Ìtàn Noa
9Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.
10Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
11Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara.
12Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye.
13Ọlọrun si wi fun Noa pe, Opin gbogbo enia de iwaju mi; nitori ti aiye kún fun ìwa-agbara lati ọwọ́ wọn; si kiye si i, emi o si pa wọn run pẹlu aiye.
14Iwọ fi igi goferi kàn ọkọ́ kan; ikele-ikele ni iwọ o ṣe ninu ọkọ́ na, iwọ o si fi ọ̀da kùn u ninu ati lode.
15Bayi ni iwọ o si ṣe e: Ìna ọkọ̀ na yio jẹ ọ̃dunrun igbọ́nwọ, ìbú rẹ̀ ãdọta igbọ́nwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọ̀nwọ.
16Ferese ni iwọ o si ṣe si ọkọ̀ na ni igbọ́nwọ kan ni ki iwọ ki o si pari wọn loke; lẹgbẹ ni iwọ o si dá ẹnu-ọ̀na ọkọ̀ na, si: pẹlu yara isalẹ, atẹle, ati ẹkẹta loke ni iwọ o ṣe e.
17Ati emi, wò o, emi nmu kikun-omi bọ̀ wá si aiye, lati pa gbogbo ohun alãye run, ti o li ẹmi ãye ninu kuro labẹ ọrun; ohun gbogbo ti o wà li aiye ni yio si kú.
18Ṣugbọn iwọ li emi o ba dá majẹmu mi; iwọ o si wọ̀ inu ọkọ̀ na, iwọ ati awọn ọmọ rẹ, ati aya rẹ, ati awọn aya awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ.
19Ati ninu ẹdá alãye gbogbo, ninu onirũru ẹran, meji meji ninu gbogbo ẹran ni iwọ o mu wọ̀ inu ọkọ̀ na, lati mu nwọn là pẹlu rẹ; ti akọ ti abo ni ki nwọn ki o jẹ.
20Ninu ẹiyẹ nipa irú ti wọn, ninu ẹran-ọ̀sin nipa irú ti wọn, ninu ohun gbogbo ti nrakò ni ilẹ nipa irú tirẹ̀, meji meji ninu gbogbo wọn ni yio ma tọ̀ ọ wá lati mu wọn wà lãye.
21Iwọ o si mu ninu ohun jijẹ gbogbo, iwọ o si kó wọn jọ si ọdọ rẹ; yio si ṣe onjẹ fun iwọ, ati fun wọn.
22Bẹ̃ni Noa si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti Ọlọrun paṣẹ fun u, bẹli o ṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Gẹn 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀