Hos 2
2
1Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama.
Gomeri Alaiṣootọ—Israẹli Alaiṣootọ
2Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀.
3Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú.
4Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère.
5Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi.
6Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ.
7On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ.
8Nitori on kò ti mọ̀ pe emi li ẹniti o fun u li ọkà, ati ọti-waini titun, ati ororo; ti mo si mu fàdakà ati wurà rẹ̀ pọ̀ si i, ti nwọn fi ṣe Baali.
9Nitorina li emi o ṣe padà, emi o si mu ọkà mi kuro li akokò rẹ̀, ati ọti-waini mi ni igbà rẹ̀, emi o si gbà irun agùtan ati ọgbọ̀ mi padà, ti mo ti fi fun u lati bò ihòho rẹ̀.
10Nisisiyi li emi o ṣi itiju rẹ̀ silẹ li oju awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ẹnikẹni kì yio si gbà a lọwọ mi.
11Emi o si mu ki gbogbo ayọ̀ rẹ̀ de opin, ọjọ asè rẹ̀, oṣù titun rẹ̀, ati ọjọ isimi rẹ̀, gbogbo ọjọ ọ̀wọ rẹ̀.
12Emi o si pa ajàra rẹ̀ ati igi ọpọ̀tọ rẹ̀ run, niti awọn ti o ti wipe, Awọn wọnyi li èrè mi ti awọn ayànfẹ́ mi ti fi fun mi; emi o si sọ wọn di igbo, awọn ẹranko igbẹ yio si jẹ wọn.
13Emi o si bẹ̀ ọjọ Baalimu wò li ara rẹ̀, ninu eyiti on fi turari joná fun wọn, ti on si fi oruka eti, ati ohun ọ̀ṣọ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọṣọ, ti on si tọ̀ awọn ayànfẹ́ lẹhìn lọ, ti on si gbagbe mi, ni Oluwa wi.
Ìfẹ́ OLUWA sí Àwọn Eniyan Rẹ̀
14Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u.
15Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá.
16Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi,
17Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́.
18Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu.
19Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu.
20Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa.
21Yio si ṣe li ọjọ na, emi o dahùn, emi o dá awọn ọrun li ohùn, nwọn o si da aiye lohùn; li Oluwa wi.
22Ilẹ yio si dá ọkà, ati ọti-waini, ati ororo, li ohùn; nwọn o si dá Jesreeli li ohùn.
23Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Hos 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.