Hos Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Apá ìhà àríwá Israẹli ni woliii Hosea ti waasu, lẹ́yìn wolii Amosi, ní àkókò ìdààmú, kí Samaria tó ṣubú ní ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mọkanlelogun kí á tó bí OLUWA wa, (721 B.C.) Ìbọ̀rìṣà àwọn eniyan náà ati ainigbagbọ ninu Ọlọrun jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún Hosea. Ó lo ìtàn iyawo rẹ̀ Gomeri, alaiṣootọ, gẹ́gẹ́ bí àfiwé àwọn eniyan Ọlọrun tí wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀. Fún ìdí èyí, ìdájọ́ yóo wá sórí Israẹli; ṣugbọn sibẹ, ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí àwọn eniyan rẹ̀ yóo borí. Yóo pe àwọn eniyan náà pada yóo sì da ibukun rẹ̀ pada sí orí wọn. Ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ yìí hàn ninu àwọn gbolohun rẹ̀; Bí àpẹẹrẹ, “Mo ṣe lè fi ọ́ sílẹ̀, Israẹli? Emi o ha ti ṣe gbà ọ silẹ Israeli? ... Ọkàn mi yí ninu mi, ìyọ́nú mi gbiná pupọ.” (11:8)
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Igbeyawo Hosea ati ìdílé rẹ̀ 1:1—3:5
Àwọn ìran ibi tí a rí sí Israẹli 4:1—13:6
Ìran nípa ìrònúpìwàdà ati ẹ̀jẹ́ 14:1-9
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Hos Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.