Isa 17
17
Ọlọrun Yóo Jẹ Siria ati Israẹli Níyà
1Ọ̀RỌ-ìmọ niti Damasku. Kiye si i, a mu Damasku kuro lati ma jẹ ilu, yi o si di òkiti àlapa.
2A kọ̀ gbogbo ilu Aroeri silẹ: nwọn o jẹ ti ọ̀wọ-ẹran, ti yio dubulẹ, ẹnikẹni kì yio dẹrubà wọn.
3Odi kì yio si si mọ ni Efraimu, ati ijọba ni Damasku, ati iyokù ti Siria: nwọn o dabi ogo awọn ọmọ Israeli, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4Li ọjọ na yio si ṣe, a o mu ogo Jakobu dinkù, ati sisanra ara rẹ̀ li a o sọ di rirù.
5Yio si dabi igbati olukorè nkó agbado jọ, ti o si nfi apá rẹ̀ rẹ́ ipẹ́-ọkà yio si dabi ẹniti nkó ipẹ́-ọkà jọ ni afonifoji Refaimu.
6Ṣugbọn ẽṣẹ́ eso-àjara yio hù ninu rẹ̀, gẹgẹ bi mimì igi olifi, eso kekere meji bi mẹta ni ṣonṣo oke ẹka mẹrin bi marun ni ẹka ode ti o ni eso pupọ, li Oluwa Ọlọrun Israeli wi.
7Li ọjọ na li ẹnikan yio wò Ẹlẹda rẹ̀, ati oju rẹ̀ yio si bọ̀wọ fun Ẹni-Mimọ Israeli.
8On kì yio si wò pẹpẹ, iṣẹ ọwọ́ rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si bọ̀wọ fun eyi ti ika rẹ̀ ti ṣe, yala igbo-òriṣa tabi ere-õrun.
9Li ọjọ na ni ilu alagbara rẹ̀ yio dabi ẹka ìkọsilẹ, ati ẹka tente oke ti nwọn fi silẹ nitori awọn ọmọ Israeli: iparun yio si wà.
10Nitori iwọ ti gbagbe Ọlọrun igbala rẹ, ti iwọ kò si nani apata agbára rẹ, nitorina ni iwọ ti gbìn ọ̀gbin daradara, iwọ si tọ́ àjeji ẹka sinu rẹ̀.
11Li ọjọ na ni iwọ o mu ki ọ̀gbin rẹ dàgba, ati li owurọ ni iwọ o mu ki irugbin rẹ rú: ṣugbọn a o mu ikorè lọ li ọjọ ini, ikãnu kikoro yio si wà.
A Ṣẹgun Àwọn Ọ̀tá
12Egbé ni fun ariwo ọ̀pọ enia, ti o pa ariwo bi ariwo okun; ati fun irọ́ awọn orilẹ-ède, ti nwọn rọ bi rirọ́ omi pupọ̀!
13Awọn orilẹ-ède yio rọ́ bi rirọ́ omi pupọ: ṣugbọn Ọlọrun yio bá wọn wi, nwọn si sa jina rere, a o si lepa wọn gẹgẹ bi ìyangbo oke-nla niwaju ẹfũfu, ati gẹgẹ bi ohun yiyi niwaju ãjà.
14Si kiye si i, li aṣalẹ, iyọnu; ki ilẹ to mọ́ on kò si. Eyi ni ipín awọn ti o kó wa, ati ipín awọn ti o jà wa li olè.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 17: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: