Isa 18
18
Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà
1EGBE ni fun ilẹ ti o ni ojiji apá meji, ti o wà ni ikọja odò Etiopia:
2Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà!
3Gbogbo ẹnyin ti ngbe aiye, ati olugbé aiye, ẹ wò, nigbati on gbe ọpagun sori awọn oke giga; ati nigbati on fọn ipè, ẹ gbọ́.
4Nitori bẹ̃li Oluwa sọ fun mi, emi o simi, emi o si gbèro ninu ibugbé mi, bi oru ọsángangan, ati bi awọsanma ìri, ninu oru ikorè.
5Nitori ṣaju ikorè, nigbati ìrudi ba kún, ti itanná ba di eso-àjara pipọn on o fi dojé rẹ́ ẹka-titun, yio si mu kuro, yio si ke ẹka lu ilẹ.
6A o si fi wọn silẹ fun awọn ẹiyẹ oke-nla, ati fun awọn ẹranko aiye: awọn ẹiyẹ yio yá õrùn lori wọn, gbogbo awọn ẹranko aiye yio si potutù lori wọn.
7Li akoko na ni a o mu ọrẹ wá fun Oluwa awọn ọmọ-ogun lati ọdọ awọn enia ti a nà ka, ti a si tẹju, ati enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá ti o tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà, si ibi orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, oke giga Sioni.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 18: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.

: