Isa 19
19
Ọlọrun Yóo Jẹ Egipti Níyà
1Ọ̀RỌ-ìmọ niti Egipti. Kiyesi i, Oluwa ngùn awọsanma ti o yara, yio si wá si Egipti: a o si ṣi ipò awọn òriṣa Egipti pàda niwaju rẹ̀, aiya Egipti yio yọ́ li ãrin rẹ̀.
2Emi o si gbe Egipti dide si Egipti: olukuluku yio si ba arakunrin rẹ̀ jà, ati olukuluku aladugbò rẹ̀; ilu yio dojukọ ilu, ati ijọba yio dojukọ ijọba.
3Ẹmi Egipti yio si rẹ̀wẹsi lãrin inu rẹ̀; emi o si pa ìmọ inu rẹ̀ run: nwọn o si wá a tọ̀ òriṣa lọ, ati sọdọ awọn atuju, ati sọdọ awọn ajẹ́, ati sọdọ awọn oṣó;
4Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Awọn ara Egipti li emi o fi le oluwa onrorò li ọwọ́; ọba ti o muna yio ṣe akoso wọn.
5Omi yio si buṣe li okun, a o si fi odò ṣofo, yio si gbẹ.
6Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ.
7Oko-tutù ni ipadò, li ẹnu odò, ati ohun gbogbo ti a gbìn sipadò, ni yio rọ, yio funka, kì yio si si mọ.
8Awọn apẹja yio gbàwẹ pẹlu, ati gbogbo awọn ti nfì ìwọ li odò yio pohùnrére-ẹkun; ati awọn ti nda àwọn li odò yio sorikọ́.
9Pẹlupẹlu awọn ti nṣiṣẹ ọ̀gbọ daradara, ati awọn ti nwun asọ-àla yio dãmu.
10A o si fọ́ wọn ni ipilẹ rẹ̀, gbogbo awọn alagbàṣe li a o bà ni inu jẹ.
11Nitõtọ òpe ni awọn ọmọ-alade Soani, ìmọ awọn ìgbimọ ọlọgbọn Farao di wère: ẹ ha ti ṣe sọ fun Farao, pe, Emi li ọmọ ọlọgbọn, ọmọ awọn ọba igbãni?
12Awọn dà? awọn ọlọgbọn rẹ dà? si jẹ ki wọn sọ fun ọ nisisiyi, si jẹ ki wọn mọ̀ ete ti Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pa le Egipti.
13Awọn ọmọ-alade Soani di aṣiwère, a tàn awọn ọmọ-alade Nofi jẹ; ani awọn ti iṣe pataki ẹyà rẹ̀.
14Oluwa ti mí ẽmi iyapa si inu rẹ̀ na: nwọn si ti mu Egipti ṣina ninu gbogbo iṣẹ inu rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀muti enia ti nta gbọngbọ́n ninu ẽbi rẹ̀.
15Bẹ̃ni kì yio si iṣẹkiṣẹ́ fun Egipti, ti ori tabi ìru, ẹka tabi oko-odò, le ṣe.
Egipti Yóo Sin OLUWA
16Li ọjọ na ni Egipti yio dabi obinrin; yio si warìri, ẹ̀ru yio si bà a nitori mimì ọwọ́ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o mì le e lori.
17Ilẹ Juda yio si di ẹ̀ru fun Egipti, olukuluku ẹniti o dá a sọ ninu rẹ̀ yio tikararẹ̀ bẹ̀ru, nitori ìmọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o ti gbà si i.
18Li ọjọ na ni ilu marun ni ilẹ Egipti yio fọ̀ ède Kenaani, ti nwọn o sì bura si Oluwa awọn ọmọ-ogun; a o ma pè ọkan ni Ilu ìparun.
19Li ọjọ na ni pẹpẹ kan yio wà fun Oluwa li ãrin ilẹ Egipti, ati ọwọ̀n ni àgbegbe inu rẹ̀ fun Oluwa.
20Yio si jẹ fun ami, ati fun ẹ̀ri si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ilẹ Egipti: nitori nwọn o kigbe pè Oluwa nitori awọn aninilara, yio si rán olugbala kan si i, ati ẹni-nla, on o si gbà wọn.
21Oluwa yio si di mimọ̀ fun Egipti, awọn ara Egipti yio so mọ́ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si rú ẹbọ, nwọn o si ta ọrẹ; nitõtọ nwọn o jẹ'jẹ fun Oluwa, nwọn o si mu u ṣẹ.
22Oluwa o si lù Egipti bolẹ, yio si mu u li ara da: nwọn o si yipada si Oluwa, on o si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn, yio si mu wọn li ara da.
23Li ọjọ na ni opopo kan yio wà lati Egipti de Assiria, awọn ara Assiria yio si wá si Egipti, awọn ara Egipti si Assiria, awọn ara Egipti yio si sìn pẹlu awọn ara Assiria.
24Li ọjọ na ni Israeli yio jẹ ẹkẹta pẹlu Egipti ati pẹlu Assiria, ani ibukún li ãrin ilẹ na:
25Ti Oluwa awọn ọmọ-ogun yio bukún fun, wipe, Ibukun ni fun Egipti enia mi, ati fun Assiria iṣẹ ọwọ́ mi, ati fun Israeli ini mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 19: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.