Isa 24
24
OLUWA Yóo Jẹ Ilẹ̀ Ayé Níyà
1KIYESI i, Oluwa sọ aiye di ofo, o si sọ ọ di ahoro, o si yi i po, o si tú awọn olugbé inu rẹ̀ ka.
2Yio si ṣe, bi o ti ri fun awọn enia, bẹ̃li o ri fun alufa; bi o ti ri fun iranṣẹ-kunrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun iranṣẹbinrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun olùra, bẹ̃ni fun olùta; bi o ti ri fun awinni, bẹ̃ni fun atọrọ; bi o ti ri fun agbà elé, bẹ̃ni fun ẹniti o san ele fun u.
3Ilẹ yio di ofo patapata, yio si bajẹ patapata: nitori Oluwa ti sọ ọ̀rọ yi.
4Ilẹ̀ nṣọ̀fọ o si nṣá, aiye nrù o si nṣá, awọn ẹni giga ilẹ njoro.
5Ilẹ pẹlu si di aimọ́ li abẹ awọn ti ngbe inu rẹ̀; nitori nwọn ti rú ofin, nwọn pa ilàna dà, nwọn dà majẹmu aiyeraiye.
6Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù.
7Ọti-waini titun nṣọ̀fọ, àjara njoro, gbogbo awọn ti nṣe aríya nkẹdùn.
8Ayọ̀ tabreti dá, ariwo awọn ti nyọ̀ pin, ayọ̀ harpu dá.
9Nwọn kì yio fi orin mu ọti-waini mọ́; ọti-lile yio koro fun awọn ti nmu u.
10A wó ilu rúdurudu palẹ: olukuluku ile li a se, ki ẹnikan má bà wọle.
11Igbe fun ọti-waini mbẹ ni igboro; gbogbo ayọ̀ ṣú òkunkun, aríya ilẹ na lọ.
12Idahoro li o kù ni ilu, a si fi iparun lù ẹnu-ibode.
13Nigbati yio ri bayi li ãrin ilẹ lãrin enia na, bi mimì igi olifi, ati bi pipẽṣẹ eso-àjara nigbati ikorè àjara tán.
14Nwọn o gbe ohùn wọn soke, nwọn o kọrin nitori ọla-nla Oluwa, nwọn o kigbe kikan lati okun wá.
15Nitorina yìn Oluwa li ogo ni ilẹ imọlẹ, ani orukọ Oluwa Ọlọrun Israeli li erekùṣu okun.
16Lati opin ilẹ li awa ti gbọ́ orin, ani ogo fun olododo. Ṣugbọn emi wipe, Iparun mi, iparun mi, egbé ni fun mi! awọn ọ̀dalẹ ti dalẹ: nitõtọ, awọn ọ̀dalẹ dalẹ rekọja.
17Ibẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati ẹgẹ́, wà lori rẹ, iwọ ti ngbe ilẹ-aiye.
18Yio si ṣe, ẹniti o sá kuro fun ariwo ìbẹru yio jin sinu ọ̀fin; ati ẹniti o jade lati inu ọ̀fin wá li a o fi ẹgẹ́ mu: nitori awọn ferese lati oke wá ṣi silẹ, ipilẹ ilẹ si mì.
19Ilẹ di fifọ́ patapata, ilẹ di yíyọ patapata, ilẹ mì tìtì.
20Ilẹ yio ta gbọ̀ngbọn sihin sọhun bi ọ̀mutí, a o si ṣi i ni idí bi agọ́; irekọja inu rẹ̀ yio wọ̀ ọ li ọrùn; yio si ṣubu, kì yio si dide mọ́.
21Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio bẹ̀ ogun awọn ẹni-giga ni ibi-giga wò, ati awọn ọba aiye li aiye.
22A o si ko wọn jọ pọ̀, bi a iti kó ara tubu jọ sinu ihò, a o tì wọn sinu tubu, lẹhin ọjọ pupọ̀ li a o si bẹ̀ wọn wò.
23Nigbana li a o dãmu oṣupa, oju yio si tì õrun, nigbati Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jọba li oke Sioni, ati ni Jerusalemu, ogo yio si wà niwaju awọn alàgba rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 24: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.