Isa 36

36
Àwọn Ará Asiria Halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu
1O si di igbati o ṣe li ọdun ikẹrinla Hesekiah ọba, Sennakeribu ọba Assiria wá dótì gbogbo ilu olodi Juda, o si kó wọn.
2Ọba Assiria si rán Rabṣake lati Lakiṣi lọ si Jerusalemu, ti on ti ogun nla, sọdọ Hesekiah ọba. O si duro lẹba idari omi abàta oke, li opopo pápa afọṣọ.
3Nigbana ni Eliakimu ọmọ Hilkia, olùtọ́ju ile, jade tọ̀ ọ wá, pẹlu Ṣebna akọwe, ati Joa ọmọ Asafu, akọwe iranti.
4Rabṣake si wi fun wọn pe, Ẹ wi fun Hesekiah nisisiyi, pe, Bayi li ọba nla, ọba Assiria wi, pe, Igbẹkẹle wo ni eyi ti iwọ gbe ara le yi?
5Iwọ wi pe, Mo ni, (ṣugbọn ọ̀rọ ète lasan ni nwọn) emi ni ìmọ ati agbara fun ogun jija: njẹ tani iwọ tilẹ gbẹkẹle ti iwọ fi nṣọ̀tẹ si mi?
6Wò o, iwọ gbẹkẹle ọpá iyè fifọ́ yi, le Egipti; eyiti bi ẹnikẹni ba fi ara tì, yio wọnu ọwọ́ rẹ̀, yio si gún u: bẹ̃ni Farao ọba Egipti ri si gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e.
7Ṣugbọn bi iwọ ba wi fun mi pe, Awa gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun wa: on kọ́ ẹniti Hesekiah ti mu ibi giga rẹ̀ wọnni, ati pẹpẹ rẹ̀, wọnni kuro, ti o si wi fun Juda ati Jerusalemu pe, ẹnyin o ma sìn niwaju pẹpẹ yi?
8Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ohun-iyàn wá fun oluwa mi ọba Assiria, emi o si fun ọ li ẹgbã ẹṣin, bi iwọ nipa tirẹ ba le ni enia to lati gùn wọn.
9Njẹ iwọ o ti ṣe le yi oju balogun kan pada ninu awọn ti o rẹhin jù ninu awọn iranṣẹ oluwa mi, ti iwọ si ngbẹkẹ rẹ le Egipti fun kẹkẹ́, ati fun ẹlẹṣin?
10Emi ha dá goke wá nisisiyi lẹhin Oluwa si ilẹ yi lati pa a run bi? Oluwa wi fun mi pe, Goke lọ si ilẹ yi, ki o si pa a run.
11Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.
12Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?
13Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria.
14Bayi ni ọba na wi, pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori on kì o lè gbà nyin.
15Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a ki o fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.
16Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀;
17Titi emi o fi wá lati mu nyin lọ si ilẹ kan bi ilẹ ẹnyin tikala nyin, ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọ̀gba àjara.
18Ẹ ṣọra ki Hesekiah ki o má pa nyin niyè dà wipe, Oluwa yio gbà wa, ọkan ninu òriṣa awọn orilẹ-ède ha gba ilẹ rẹ̀ lọwọ ọba Assiria ri bi?
19Nibo li awọn òriṣa Hamati on Arfardi gbe wà? Nibo li awọn òriṣa Sefarfaimu wà? nwọn ha si ti gbà Samaria li ọwọ́ mi bi?
20Tani ninu gbogbo oriṣa ilẹ wọnyi, ti o ti gbà ilẹ wọn kuro li ọwọ́ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro li ọwọ́ mi?
21Ṣugbọn nwọn dakẹ, nwọn kò si da a lohùn ọ̀rọ kan: nitoriti aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a lohùn.
22Nigbana ni Eliakimu, ọmọ Hilkia, ti iṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa, ọmọ Asafu akọwe iranti, wá sọdọ Hesekiah ti awọn ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 36: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀