Isa 41:19-20

Isa 41:19-20 YBCV

Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù. Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.