Isa 41:19-20
Isa 41:19-20 Yoruba Bible (YCE)
N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀. Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀, kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀, pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”
Isa 41:19-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o fi igi kedari si aginjù, ati igi ṣita, ati mirtili, ati igi oróro; emi o gbìn igi firi ati igi pine ati igi boksi pọ̀ ni aginjù. Ki nwọn ki o le ri, ki nwọn ki o si mọ̀, ki nwọn si gbèro, ki o si le yé won pọ̀, pe, ọwọ́ Oluwa li o ti ṣe eyi, ati pe Ẹni-Mimọ Israeli ni o ti dá a.
Isa 41:19-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀ igi kedari àti kasia, maritili àti olifi. Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù, igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀, kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn, pé ọwọ́ OLúWA ni ó ti ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.