Isa 54

54
Ìfẹ́ OLUWA sí Israẹli
1KỌRIN, iwọ àgan, ti kò bi ri; bú si orin, si ké rara, iwọ ti kò rọbi ri; nitori awọn ọmọ ẹni-alahoro pọ̀ ju awọn ọmọ ẹniti a gbe ni iyawo: li Oluwa wi.
2Sọ ibi agọ rẹ di gbigbõro, si jẹ ki wọn nà aṣọ tita ibugbe rẹ̀ jade: máṣe dási, sọ okùn rẹ di gigùn, ki o si mu ẽkàn rẹ le.
3Nitori iwọ o ya si apa ọtún ati si apa osì, iru-ọmọ rẹ yio si jogun awọn keferi: nwọn o si mu ki awọn ilu ahoro wọnni di ibi gbigbe.
4Má bẹ̀ru, nitori oju kì yio tì ọ: bẹ̃ni ki o máṣe dãmu; nitori a ki yio doju tì ọ; nitori iwọ o gbagbe itìju igbà ewe rẹ, iwọ kì yio sì ranti ẹ̀gan iwà-opo rẹ mọ.
5Nitori Ẹlẹda rẹ li ọkọ rẹ; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀; ati Olurapada rẹ Ẹni-Mimọ Israeli; Ọlọrun agbaiye li a o ma pè e.
6Nitori Oluwa ti pè ọ bi obinrin ti a kọ̀ silẹ, ti a si bà ni inu jẹ, ati bi aya igba ewe nigbati a ti kọ̀ ọ, li Ọlọrun rẹ wi.
7Ni iṣẹju diẹ ni mo ti kọ̀ ọ silẹ, ṣugbọn li ãnu nla li emi o kó ọ jọ:
8Ni ṣiṣàn ibinu li emi pa oju mi mọ kuro lara rẹ ni iṣẹju kan! ṣugbọn õre ainipẹkun li emi o fi ṣãnu fun ọ; li Oluwa Olurapada rẹ wí.
9Nitori bi awọn omi Noa li eyi ri si mi, nitori gẹgẹ bi mo ti bura pe omi Noa kì yio bò aiye mọ, bẹ̃ni mo si ti bura pe emi kì yio binu si ọ, bẹ̃ni emi kì yio ba ọ wi.
10Nitori awọn oke-nla yio ṣi lọ, a o si ṣi awọn oke kékèké ni idi, ṣugbọn ore mi kì yio fi ọ silẹ, bẹ̃ni emi kì yio ṣi majẹmu alafia mi ni ipò: li Oluwa wi, ti o ṣãnu fun ọ.
Ọjọ́ Iwájú Jerusalẹmu
11Iwọ ẹniti a npọ́n loju, ti a si nfi ijì gbákiri, ti a kò si tù ninu, wò o, emi o fi tìrõ tẹ́ okuta rẹ, emi o si fi safire fi ipilẹ rẹ le ilẹ.
12Emi o fi rubi ṣe ṣonṣo-ile rẹ, emi o si fi okuta didán ṣe àsẹ rẹ; emi o si fi awọn okuta àṣayan ṣe agbègbe rẹ.
13A o si kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa wá; alafia awọn ọmọ rẹ yio si pọ̀.
14Ninu ododo li a o fi idi rẹ mulẹ: iwọ o jina si inira; nitori iwọ kì yio bẹ̀ru: ati si ifoiya, nitori kì yio sunmọ ọ.
15Kiye si i, ni kikojọ nwọn o kó ara wọn jọ, ṣugbọn ki iṣe nipasẹ mi; ẹnikẹni ti o ba ditẹ si ọ yio ṣubu nitori rẹ.
16Kiye si i, emi li ẹniti o ti dá alagbẹ̀dẹ ti nfẹ́ iná ẹyín, ti o si mu ohun-elò jade fun iṣẹ rẹ̀; emi li o si ti dá apanirun lati panirun.
17Kò si ohun-ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan; ati gbogbo ahọn ti o dide si ọ ni idajọ ni iwọ o da li ẹbi. Eyi ni ogún awọn iranṣẹ Oluwa, lati ọdọ mi ni ododo wọn ti wá, li Oluwa wi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 54: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀