Isa 56
56
Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun
1BAYI li Oluwa wi, Ẹ pa idajọ mọ, ẹ si ṣe ododo: nitori igbala mi fẹrẹ idé, ati ododo mi lati fi hàn.
2Alabukun ni fun ọkunrin na ti o ṣe eyi, ati fun ọmọ enia ti o dì i mu: ti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́; ti o si pa ọwọ́ rẹ̀ mọ kuro ni ṣiṣe ibi.
3Ti kò si jẹ ki ọmọ alejò ti o ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Oluwa sọ, wipe; Oluwa ti yà mi kuro ninu awọn enia rẹ̀ patapata: bẹ̃ni kò jẹ ki ìwẹ̀fà wipe, Wò o, igi gbigbẹ ni mi.
4Nitori bayi li Oluwa wi fun awọn ìwẹfa ti nwọn pa ọjọ isimi mi mọ, ti nwọn si yàn eyi ti o wù mi, ti nwọn si di majẹmu mi mu;
5Pe, emi o fi ipò kan fun wọn ni ile mi, ati ninu odi mi, ati orukọ ti o dara jù ti awọn ọmọkunrin ati ọmọ-obinrin lọ: emi o fi orukọ ainipẹkun fun wọn, ti a kì yio ke kuro.
6Ati awọn ọmọ alejò ti nwọn dà ara pọ̀ mọ Oluwa, lati sìn i, ati lati fẹ orukọ Oluwa, lati jẹ iranṣẹ rẹ̀, olukuluku ẹniti o pa ọjọ isimi mọ laisọ ọ di aimọ́, ti o si di majẹmu mi mu;
7Awọn li emi o si mu wá si oke-nla mimọ́ mi, emi o si mu inu wọn dùn, ninu ile adua mi: ẹbọ sisun wọn, ati irubọ wọn, yio jẹ itẹwọgba lori pẹpẹ mi; nitori ile adua li a o ma pe ile mi fun gbogbo enia.
8Oluwa Jehofah, ẹniti o ṣà àtanu Israeli jọ wipe, Emi o ṣà awọn ẹlomiran jọ sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ti a ti ṣà jọ sọdọ rẹ̀.
A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli Lẹ́bi
9Gbogbo ẹnyin ẹranko igbẹ, ẹ wá lati pajẹ ani gbogbo ẹranko igbẹ.
10Afọju li awọn alore rẹ̀: òpe ni gbogbo wọn, odi ajá ni nwọn, nwọn kò le igbó, nwọn a ma sùn, nwọn ndubulẹ, nwọn fẹ ma tõgbé.
11Nitõtọ ọjẹun aja ni nwọn ti kì iyó, ati oluṣọ́ agutan ti kò moye ni nwọn: olukuluku wọn nwò ọ̀na ara wọn, olukuluku ntọju ere rẹ̀ lati ẹ̀kun rẹ̀ wá.
12Ẹ wá, ni nwọn wi, emi o mu ọti-waini wá, a o si mu ọti-lile li amuyo; ọla yio si dabi ọjọ oni, yio si pọ̀ lọpọlọpọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 56: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.