Jer 31
31
Israẹli Pada sílé
1LI àkoko na, li Oluwa wi, li emi o jẹ Ọlọrun gbogbo idile Israeli, nwọn o si jẹ enia mi.
2Bayi li Oluwa wi, Enia ti o sala lọwọ idà ri ore-ọfẹ li aginju, ani Israeli nigbati emi lọ lati mu u lọ si isimi rẹ̀.
3Oluwa ti fi ara hàn fun mi lati okere pe, Nitõtọ emi fi ifẹni aiyeraiye fẹ ọ, nitorina ni emi ti ṣe pa ore-ọfẹ mọ fun ọ.
4Emi o tun ọ kọ́, iwọ o si di kikọ, iwọ wundia Israeli! iwọ o si fi timbreli rẹ ṣe ara rẹ lọṣọ, iwọ o si jade lọ ni ọwọ́-ijo ti awọn ti nyọ̀.
5Iwọ o gbìn ọgba-ajara sori oke Samaria: awọn àgbẹ yio gbìn i, nwọn o si jẹ ẹ.
6Nitori ọjọ na ni eyi, ti awọn oluṣọ lori oke Efraimu yio kigbe pe, Ẹ dide, ẹ si jẹ ki a goke lọ si Sioni sọdọ Oluwa, Ọlọrun wa.
7Nitori bayi li Oluwa wi; ẹ fi ayọ̀ kọrin didùn fun Jakobu, ẹ si ho niti olori awọn orilẹ-ède: ẹ kede! ẹ yìn, ki ẹ si wipe: Oluwa, gbà awọn enia rẹ la, iyokù Israeli!
8Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ.
9Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi.
10Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀.
11Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ.
12Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara.
13Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.
14Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.
Àánú OLUWA lórí Israẹli
15Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.
16Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.
17Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn.
18Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi.
19Lõtọ lẹhin ti emi yipada, mo ronupiwada; ati lẹhin ti a kọ́ mi, mo lu ẹ̀gbẹ mi: oju tì mi, lõtọ, ani mo dãmu, nitoripe emi ru ẹ̀gan igba ewe mi.
20Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.
21Gbe àmi-ọ̀na soke, ṣe ọwọ̀n àmi: gbe ọkàn rẹ si opopo ọ̀na, ani ọ̀na ti iwọ ti lọ: tun yipada, iwọ wundia Israeli, tun yipada si ilu rẹ wọnyi.
22Iwọ o ti ṣina kiri pẹ to, iwọ apẹhinda ọmọbinrin? nitori Oluwa dá ohun titun ni ilẹ na pe, Obinrin kan yio yi ọkunrin kan ka.
Ọjọ́ Iwájú Àwọn Eniyan Ọlọrun Yóo Dára
23Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́!
24Juda ati gbogbo ilu rẹ̀ yio ma jumọ gbe inu rẹ̀, agbẹ, ati awọn ti mba agbo-ẹran lọ kakiri,
25Nitori emi tù ọkàn alãrẹ ninu, emi si ti tẹ gbogbo ọkàn ikãnu lọrun.
26Lori eyi ni mo ji, mo si wò; õrun mi si dùn mọ mi.
27Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbin ile Israeli ati Judah ni irugbin enia, ati irugbin ẹran.
28Yio si ṣe, pe gẹgẹ bi emi ti ṣọ́ wọn, lati fà tu, ati lati fa lulẹ, ati lati wo lulẹ, ati lati parun, ati lati pọnloju, bẹ̃ni emi o ṣọ́ wọn, lati kọ́, ati lati gbìn, li Oluwa wi.
29Li ọjọ wọnni, nwọn kì yio wi mọ pe, Awọn baba ti jẹ eso ajara aipọn, ehín si ti kan awọn ọmọ.
30Ṣugbọn olukuluku ni yio kú nitori aiṣedede rẹ̀, olukuluku ti o jẹ eso ajara-aipọn ni ehín yio kan.
31Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o ba ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.
32Kì iṣe bi majẹmu na ti emi ba baba wọn dá li ọjọ na ti emi fà wọn lọwọ lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti: awọn ti nwọn dà majẹmu mi, bi emi tilẹ jẹ alakoso wọn sibẹ, li Oluwa wi;
33Ṣugbọn eyi ni majẹmu ti emi o ba ile Israeli da; Lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi, emi o fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ ọ si aiya wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, awọn o si jẹ enia mi.
34Nwọn kì yio si kọni mọ ẹnikini ẹnikeji rẹ̀, ati ẹ̀gbọn, aburo rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo nwọn ni yio mọ̀ mi, lati ẹni-kekere wọn de ẹni-nla wọn, li Oluwa wi; nitori emi o dari aiṣedede wọn ji, emi kì o si ranti ẹ̀ṣẹ wọn mọ.
35Bayi li Oluwa wi ti o fi õrùn fun imọlẹ li ọsan, ilana oṣupa ati irawọ fun imọlẹ li oru, ti o rú okun soke tobẹ̃, ti riru omi rẹ̀ nho; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀:
36Bi ilana wọnyi ba yẹ̀ kuro niwaju mi, li Oluwa wi, njẹ iru-ọmọ Israeli pẹlu yio dẹkun lati ma jẹ orilẹ-ède niwaju mi lailai.
37Bayi li Oluwa wi, Bi a ba le wọ̀n ọrun loke, ti a si le wá ipilẹ aiye ri nisalẹ, emi pẹlu yio ta iru-ọmọ Israeli nù nitori gbogbo eyiti nwọn ti ṣe, li Oluwa wi.
38Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti a o kọ́ ilu na fun Oluwa lati ile-iṣọ Hananeeli de ẹnu-bode igun odi.
39Okùn ìwọn yio si nà jade siwaju lẹba rẹ̀ lori oke Garebi, yio si lọ yi Goati ka.
40Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 31: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.