Jer 34

34
Iṣẹ́ tí A Rán sí Sedekiah
1Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, ni wakati ti Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀, ati gbogbo ijọba ilẹ-ijọba ọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn orilẹ-ède, mba Jerusalemu ati gbogbo ilu rẹ̀ ja, wipe:
2Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi: Lọ, ki o si sọ fun Sedekiah, ọba Juda, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si fi iná kun u:
3Iwọ kì o si le sala kuro lọwọ rẹ̀, ṣugbọn ni mimú a o mu ọ, a o si fi ọ le e lọwọ; oju rẹ yio si ri oju ọba Babeli, on o si ba ọ sọ̀rọ lojukoju, iwọ o si lọ si Babeli.
4Sibẹ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, iwọ Sedekiah, ọba Juda: Bayi li Oluwa wi niti rẹ, Iwọ kì yio ti ipa idà kú.
5Iwọ o kú li alafia: ati bi ijona-isinkú awọn baba rẹ, awọn ọba igbãni ti o wà ṣaju rẹ, bẹ̃ni nwọn o si ṣe ijona-isinkú fun ọ, nwọn o si pohunrere rẹ, pe, Yẽ oluwa! nitori eyi li ọ̀rọ ti emi ti sọ, li Oluwa wi.
6Jeremiah woli, si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun Sedekiah, ọba Juda ni Jerusalemu.
7Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.
Wọ́n Rẹ́ Àwọn Ẹrú Jẹ
8Ọ̀rọ ti o tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa lẹhin ti Sedekiah, ọba, ti ba gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu dá majẹmu, lati kede omnira fun wọn.
9Pe, ki olukuluku enia le jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia, iranṣẹbinrin rẹ̀, ti iṣe ọkunrin Heberu tabi obinrin Heberu, lọ lọfẹ; ki ẹnikẹni ki o má mu ara Juda, arakunrin rẹ̀, sìn.
10Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ.
11Ṣugbọn lẹhin na nwọn yi ọkàn pada, nwọn si mu ki awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, awọn ẹniti nwọn ti jẹ ki o lọ lọfẹ, ki o pada, nwọn si mu wọn sin bi iranṣẹkunrin ati bi iranṣẹbinrin.
12Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, wipe,
13Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe,
14Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ.
15Ẹnyin si yi ọkàn pada loni, ẹ si ti ṣe eyi ti o tọ li oju mi, ni kikede omnira, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀; ẹnyin si ti dá majẹmu niwaju mi ni ile ti a fi orukọ mi pè:
16Ṣugbọn ẹnyin yipada, ẹ si sọ orukọ mi di ẽri, olukuluku enia si mu ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia iranṣẹbinrin rẹ̀, ti on ti sọ di omnira ni ifẹ wọn, ki o pada, ẹnyin si mu wọn sìn lati jẹ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, fun nyin.
17Nitorina bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò feti si mi, ni kikede omnira, ẹgbọ́n fun aburo rẹ̀, ati ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀: wò o, emi o kede omnira fun nyin, li Oluwa wi, si idà, si ajakalẹ-àrun, ati si ìyan, emi o si fi nyin fun iwọsi ni gbogbo ijọba ilẹ aiye.
18Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀,
19Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na;
20Emi o fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: okú wọn yio si jẹ onjẹ fun awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun awọn ẹranko igbẹ.
21Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin.
22Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 34: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀