Joh 1
1
Ọlọrun di Eniyan
1LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.
2On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun.
3Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.
4Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.
5Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.
6Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu.
7On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.
8On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na.
9Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.
10On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ.
11O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a.
12Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́:
13Awọn ẹniti a bí, kì iṣe nipa ti ẹ̀jẹ, tabi nipa ti ifẹ ara, bẹ̃ni kì iṣe nipa ifẹ ti enia, bikoṣe nipa ifẹ ti Ọlọrun.
14Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.
15Johanu si jẹri rẹ̀ o si kigbe, wipe, Eyi ni ẹniti mo sọrọ rẹ̀ pe, Ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, o pọ̀ju mi lọ: nitori o wà ṣiwaju mi.
16Nitori ninu ẹkún rẹ̀ ni gbogbo wa si ti gbà, ati ore-ọfẹ kún ore-ọfẹ.
17Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.
18Ko si ẹniti o ri Ọlọrun rí; Ọmọ bíbi kanṣoṣo, ti mbẹ li õkan àiya Baba, on na li o fi i hàn.
Ẹ̀rí Johanu Onítẹ̀bọmi nípa Jesu
(Mat 3:1-12; Mak 1:1-8; Luk 3:1-18)
19Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?
20O si jẹwọ, kò si sẹ́; o si jẹwọ pe, Emi kì iṣe Kristi na.
21Nwọn si bi i pe, Tani iwọ ha iṣe? Elijah ni ọ bi? O si wipe Bẹ̃kọ. Iwọ ni woli na bi? O si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.
22Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? ki awa ki o le fi èsi fun awọn ti o rán wa. Kili o wi ni ti ara rẹ?
23O wipe, Emi li ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ ṣe ki ọ̀na Oluwa tọ́, gẹgẹ bi woli Isaiah ti wi.
24Awọn ti a rán si jẹ ninu awọn Farisi.
25Nwọn si bi i lẽre, nwọn si wi fun u pe, Njẹ ẽṣe ti iwọ fi mbaptisi, bi iwọ kì ibá ṣe Kristi na, tabi Elijah, tabi woli na?
26Johanu da wọn lohùn, wipe, Emi nfi omi baptisi: ẹnikan duro larin nyin, ẹniti ẹnyin kò mọ̀;
27On na li ẹniti mbọ̀ lẹhin mi, ti o pọju mi lọ, ẹniti emi kò yẹ lati tú okùn bàta rẹ̀.
28Nkan wọnyi li a ṣe ni Betani loke odò Jordani, nibiti Johanu gbé mbaptisi.
Ọ̀dọ́ Aguntan Ọlọrun Farahàn
29Ni ijọ keji Johanu ri Jesu mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀; o wipe, Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó ẹ̀ṣẹ aiye lọ!
30Eyi li ẹniti mo ti wipe, ọkunrin kan mbọ̀ wá lẹhin mi, ẹniti o pọ̀ju mi lọ: nitoriti o ti wà ṣiwaju mi.
31Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ki a le fi i hàn fun Israeli, nitorina li emi ṣe wá ti mo nfi omi baptisi.
32Johanu si jẹri, o wipe, mo ri Ẹmi sọkalẹ lati ọrun wá bi àdaba, o si bà le e.
33Emi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹniti o rán mi wá, lati fi omi baptisi, on na li o wi fun mi pe, Lori ẹniti iwọ ba ri, ti Ẹmí sọkalẹ si, ti o si bà le e, on na li ẹniti nfi Ẹmí Mimọ́ baptisi.
34Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.
Àwọn Ọmọ-Ẹ̀hìn Kinni tí Jesu Ní
35Ni ijọ keji ẹwẹ Johanu duro, ati meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀:
36O si wò Jesu bi o ti nrìn, o si wipe, Wò Ọdọ-agutan Ọlọrun!
37Awọn ọmọ-ẹhin meji na si gbọ́ nigbati o wi, nwọn si tọ̀ Jesu lẹhin.
38Nigbana ni Jesu yipada, o ri nwọn ntọ̀ on lẹhin, o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nwá? Nwọn wi fun u pe, Rabbi, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Olukọni,) nibo ni iwọ ngbé?
39O wi fun wọn pe, Ẹ wá wò o. Nwọn si wá, nwọn si ri ibi ti o ngbé, nwọn si ba a joko ni ijọ na: nitoriti o jẹ ìwọn wakati kẹwa ọjọ.
40Ọkan ninu awọn meji ti o gbọ́ ọ̀rọ Johanu, ti o si tọ̀ Jesu lẹhin, ni Anderu, arakunrin Simoni Peteru.
41On tètekọ ri Simoni arakunrin on tikararẹ̀, o si wi fun u pe, Awa ti ri Messia, itumọ̀ eyi ti ijẹ Kristi.
42O si mu u wá sọdọ Jesu. Jesu si wò o, o wipe, Iwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa li a o si ma pè ọ, itumọ̀ eyi ti ijẹ Peteru.
Jesu Pe Filipi ati Natanaeli
43Ni ọjọ keji Jesu nfẹ jade lọ si Galili, o si ri Filippi, o si wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin.
44Ara Betsaida ni Filippi iṣe, ilu Anderu ati Peteru.
45Filippi ri Natanaeli, o si wi fun u pe, Awa ti ri ẹniti Mose ninu ofin ati awọn woli ti kọwe rẹ̀, Jesu ti Nasareti, ọmọ Josefu.
46Natanaeli si wi fun u pe, Ohun rere kan ha le ti Nasareti jade? Filippi wi fun u pe, Wá wò o.
47Jesu ri Natanaeli mbọ̀ wá sọdọ rẹ̀, o si wi nipa rẹ̀ pe, Wo o, ọmọ Israelì nitõtọ, ninu ẹniti ẹ̀tan kò si!
48Natanaeli wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti mọ̀ mi? Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ki Filippi to pè ọ, nigbati iwọ wà labẹ igi ọ̀pọ́tọ, mo ti ri ọ.
49Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli.
50Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Nitori mo wi fun ọ pe, mo ri ọ labẹ igi ọpọtọ ni iwọ ṣe gbagbọ? iwọ ó ri ohun ti o pọ̀ju wọnyi lọ.
51O si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnyin o ri ọrun ṣí silẹ, awọn angẹli Ọlọrun yio si ma gòke, nwọn o si ma sọkalẹ sori Ọmọ-enia.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joh 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.