Joh 20
20
Ajinde Jesu
1LI ọjọ ikini ọ̀sẹ ni kùtùkùtù nigbati ilẹ kò ti imọ́, ni Maria Magdalene wá si ibojì, o si ri pe, a ti gbé okuta kuro li ẹnu ibojì.
2Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.
3Nigbana ni Peteru jade, ati ọmọ-ẹhin miran na, nwọn si wá si ibojì.
4Awọn mejeji si jùmọ sare: eyi ọmọ-ẹhin miran nì si sare yà Peteru, o si tètekọ de ibojì.
5O si bẹ̀rẹ, o si wò inu rẹ̀, o ri aṣọ ọgbọ na lelẹ; ṣugbọn on kò wọ̀ inu rẹ̀.
6Nigbana ni Simoni Peteru ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀ de, o si wọ̀ inu ibojì, o si ri aṣọ ọ̀gbọ na wà nilẹ̀.
7Ati pe gèle, ti o wà nibi ori rẹ̀, kò si wà pẹlu aṣọ ọgbọ na, ṣugbọn a ká a jọ ni ibikan fun ara rẹ̀.
8Nigbana li ọmọ-ẹhin miran na, ẹniti o kọ de ibojì, wọ̀ inu rẹ̀ pẹlu, o si ri, o si gbagbọ́.
9Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú.
10Bẹli awọn ọmọ-ẹhin na si tun pada lọ si ile wọn.
Jesu Fara Han Maria Magidaleni
(Mat 28:9-10; Mak 16:9-11)
11Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì.
12O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si.
13Nwọn si wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? O si wi fun wọn pe, Nitoriti nwọn ti gbé Oluwa mi, emi kò si mọ̀ ibiti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.
14Nigbati o si ti wi eyi tan, o yipada, o si ri Jesu duro, kò si mọ̀ pe Jesu ni.
15Jesu wi fun u pe, Obinrin yi, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? Ta ni iwọ nwá? On ṣebi oluṣọgba ni iṣe, o wi fun u pe, Alàgba, bi iwọ ba ti gbé e kuro nihin, sọ ibiti o gbé tẹ ẹ si fun mi, emi o si gbé e kuro.
16Jesu wi fun u pe, Maria. O si yipada, o wi fun u pe, Rabboni; eyi ti o jẹ Olukọni.
17Jesu wi fun u pe, Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi: ṣugbọn lọ sọdọ awọn arakunrin mi, si wi fun wọn pe, Emi ngòke lọ sọdọ Baba mi, ati Baba nyin; ati sọdọ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun nyin.
18Maria Magdalene wá, o si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin pe, on ti ri Oluwa, ati pe, o si ti sọ nkan wọnyi fun on.
Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn
(Mat 28:16-20; Mak 16:14-18; Luk 24:36-49)
19Lọjọ kanna, lọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati alẹ́ lẹ́, ti a si ti tì ilẹkun ibiti awọn ọmọ-ẹhin gbé pejọ, nitori ìbẹru awọn Ju, bẹni Jesu de, o duro larin, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin.
20Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o fi ọwọ́ ati ìha rẹ̀ hàn wọn. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin yọ̀, nigbati nwọn ri Oluwa.
21Nitorina Jesu si tún wi fun wọn pe, Alafia fun nyin: gẹgẹ bi Baba ti rán mi, bẹ̃li emi si rán nyin.
22Nigbati o si ti wi eyi tan, o mí si wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbà Ẹmí Mimọ́:
23 Ẹṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba fi jì, a fi ji wọn; ẹ̀ṣẹ ẹnikẹni ti ẹnyin ba da duro, a da wọn duro.
Tomasi Kò Kọ́kọ́ Gbàgbọ́
24Ṣugbọn Tomasi, ọkan ninu awọn mejila, ti a npè ni Didimu, kò wà pẹlu wọn nigbati Jesu de.
25Nitorina awọn ọmọ-ẹhin iyokù wi fun u pe, Awa ti ri Oluwa. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣo li ọwọ́ rẹ̀ ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ́ mi si ìha rẹ̀, emi kì yio gbagbó.
26Lẹhin ijọ mẹjọ awọn ọmọ-ẹhin si tún wà ninu ile, ati Tomasi pẹlu wọn: nigbati a si ti tì ilẹkun, Jesu de, o si duro larin, o si wipe, Alafia fun nyin.
27Nigbana li o wi fun Tomasi pe, Mu ika rẹ wá nihin, ki o si wò ọwọ́ mi; si mu ọwọ́ rẹ wá nihin, ki o si fi si ìha mi: kì iwọ ki o máṣe alaigbagbọ́ mọ́, ṣugbọn jẹ onigbagbọ.
28Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi!
29Jesu wi fun u pe, Nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ́: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti nwọn si gbagbọ́.
Èrèdí Ìwé Ìyìn Rere yìí
30Ọpọlọpọ iṣẹ àmi miran ni Jesu ṣe niwaju awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ti a kò kọ sinu iwe yi:
31Ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ́, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joh 20: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.