Joh 9
9
Jesu Wo Ẹni tí Wọ́n Bí Ní Afọ́jú Sàn
1BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá.
2Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?
3Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.
4 Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ.
5 Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.
6Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na,
7O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran.
8Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi?
9Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni.
10Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là?
11O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.
12Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.
Àwọn Farisi Wádìí Ìwòsàn Afọ́jú Náà
13Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi.
14Njẹ ọjọ isimi lọjọ na nigbati Jesu ṣe amọ̀ na, ti o si là a loju.
15Nitorina awọn Farisi pẹlu tún bi i lẽre, bi o ti ṣe riran. O si wi fun wọn pe, O fi amọ̀ le oju mi, mo si wẹ̀ mo si riran.
16Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn.
17Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe.
18Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju.
19Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi?
20Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju:
21Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.
22Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.
23Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre.
24Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe.
25Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi.
26Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju?
27O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi?
28Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa.
29Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá.
30Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju.
31Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀.
32Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí.
33Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun.
34Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode.
35Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi?
36On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́?
37Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi.
38O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u.
39Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju.
40Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi?
41Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joh 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.