Job 16
16
1NIGBANA ni Jobu dahùn o si wipe,
2Emi ti gbọ́ iru ohun pipọ bẹ̃ ri; ayọnilẹnu onitunu enia ni gbogbo nyin.
3Ọ̀rọ asan lè ni opin? tabi kili o gbó ọ laiya ti iwọ fi dahùn.
4Emi pẹlu le isọ bi ẹnyin, bi ọkàn nyin ba wà ni ipò ọkàn mi, emi le iko ọ̀rọ pọ̀ si nyin li ọrùn, emi a si mì ori mi si nyin.
5Emi iba fi ọ̀rọ ẹnu mi gbà nyin ni iyanju, ati ṣiṣi ète mi iba si tu ibinujẹ nyin.
6Bi emi tilẹ sọ̀rọ ibinujẹ mi kò rù; bi mo si tilẹ dakẹ, nibo li itunu mi de?
7Ṣugbọn nisisiyi, o da mi lagara, iwọ (Ọlọrun) mu gbogbo ẹgbẹ mi takete.
8Iwọ si fi ikiweje kún mi lara, ti o jẹri tì mi; ati rirù ti o yọ lara mi, o jẹri tì mi li oju.
9Ibinu rẹ̀ li o fà mi ya, o si ṣọta mi; o pa ehin rẹ̀ keke si mi, ọta mi si gboju rẹ̀ si mi.
10Nwọn ti fi ẹnu wọn yán si mi, nwọn gbá mi li ẹrẹkẹ ni igbá ẹ̀gan, nwọn kó ara wọn jọ pọ̀ si mi.
11Ọlọrun ti fi mi le ọwọ ẹni-buburu, o si mu mi ṣubu si ọwọ enia ẹlẹṣẹ.
12Mo ti joko jẹ, ṣugbọn o fa mi já o si dì mi li ọrùn mu, o si gbọ̀n mi tutu, o si gbe mi kalẹ ṣe àmi itasi rẹ̀.
13Awọn tafatafa rẹ̀ duro yi mi kakiri; o là mi laiya pẹ̀rẹ kò si dasi, o si tú orõrò ara mi dà silẹ.
14Ibajẹ lori ibajẹ li o fi ba mi jẹ; o sure kọlù mi bi òmirán.
15Mo rán aṣọ-apo bò ara mi, mo si rẹ̀ iwo mi silẹ ninu erupẹ.
16Oju mi ti pọ́n fun ẹkún, ojiji ikú si ṣẹ si ipenpeju mi.
17Kì iṣe nitori aiṣotitọ kan li ọwọ mi, adura mi si mọ́ pẹlu.
18A! ilẹ aiye, iwọ máṣe bò ẹ̀jẹ mi, ki ẹkún mi máṣe ni ipò kan.
19Njẹ nisisiyi kiyesi i! ẹlẹri mi mbẹ li ọrun, ẹri mi si mbẹ loke ọrun.
20Awọn ọre mi nfi mi ṣẹ̀sin, ṣugbọn oju mi ndà omije sọdọ Ọlọrun.
21Ibaṣepe ẹnikan le ma ṣe alagbawi fun ẹnikeji lọdọ Ọlọrun, bi enia kan ti iṣe alagbawi fun ẹnikeji rẹ̀.
22Nitori nigbati iye ọdun diẹ rekọja tan, nigbana ni emi o lọ si ibi ti emi kì yio pada bọ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 16: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.