Job 21
21
1SUGBỌN Jobu dahùn, o si wipe,
2Ẹ tẹti silẹ dẹdẹ si ohùn mi, ki eyi ki o jasi itunu nyin.
3Ẹ jọwọ mi ki emi sọ̀rọ, lẹhin igbati mo ba sọ tan, iwọ ma fi ṣẹsin nṣo.
4Bi o ṣe ti emi ni, aroye mi iṣe si enia bi, tabi ẽtiṣe ti ọkàn mi kì yio fi ṣe aibalẹ?
5Ẹ wò mi fin, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki ẹ si fi ọwọ le ẹnu nyin.
6Ani nigbati mo ranti, ẹ̀ru bà mi, iwarìri si mu mi lara.
7Nitori kini enia buburu fi wà li ãyè, ti nwọn gbọ́, ani ti nwọn di alagbara ni ipa!
8Iru-ọmọ wọn fi idi kalẹ li oju wọn pẹlu wọn, ati ọmọ-ọmọ wọn li oju wọn.
9Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn.
10Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu;
11Nwọn a ma rán awọn ọmọ wọn wẹwẹ jade bi agbo ẹran, awọn ọmọ wọn a si ma jó.
12Nwọn mu ohun ọnà orin timbreli ati dùru, nwọn si nyọ̀ si ohùn ifère.
13Nwọn lo ọjọ wọn ninu ọrọ̀; ni iṣẹjukan nwọn a lọ si ipo-okú.
14Nitorina ni nwọn ṣe wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa, nitoripe awa kò fẹ ìmọ ipa ọ̀na rẹ!
15Kini Olodumare ti awa o fi ma sin i? ere kili a o si jẹ bi awa ba gbadura si i!
16Kiyesi i, alafia wọn kò si nipa ọwọ wọn, ìmọ enia buburu jina si mi rére.
17Igba melomelo ni a npa fitila enia buburu kú? igba melomelo ni iparun wọn de ba wọn, ti Ọlọrun isi ma pin ibinujẹ ninu ibinu rẹ̀.
18Nwọn dabi akeku oko niwaju afẹfẹ, ati bi iyangbo, ti ẹfufu-nla fẹ lọ.
19Ọlọrun to ìya-ẹ̀ṣẹ rẹ̀ jọ fun awọn ọmọ rẹ̀, o san a fun u, yio si mọ̀ ọ.
20Oju rẹ̀ yio ri iparun ara rẹ̀, yio si ma mu ninu riru ibinu Olodumare.
21Nitoripe alafia kili o ni ninu ile rẹ̀ lẹhin rẹ̀, nigbati a ba ke iye oṣù rẹ̀ kuro li agbedemeji?
22Ẹnikẹni le ikọ́ Ọlọrun ni ìmọ? on ni sa nṣe idajọ ẹni ibi giga.
23Ẹnikan a kú ninu pipé agbara rẹ̀, ti o wà ninu irọra ati idakẹ patapata.
24Ọpọ́n rẹ̀ kún fun omi-ọmú, egungun rẹ̀ si tutu fun ọra.
25Ẹlomiran a si kú ninu kikoro ọkàn rẹ̀, ti kò si fi inu didun jẹun.
26Nwọn o dubulẹ bakanna ninu erupẹ, kòkoro yio si ṣùbo wọn.
27Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi.
28Nitoriti ẹnyin wipe, nibo ni ile awọn ọmọ alade, ati nibo ni agọ awọn enia buburu nì gbe wà?
29Ẹnyin kò bere lọwọ awọn ti nkọja lọ li ọ̀na, ẹnyin kò mọ̀ àmi wọn? pe,
30Enia buburu ni a fi pamọ fun ọjọ iparun, a o si mu wọn jade li ọjọ riru ibinu.
31Tani yio sọ ipa-ọ̀na rẹ̀ kò o li oju, tani yio si san pada fun u li eyi ti o ti ṣe?
32Sibẹ a o si sin i li ọ̀na ipo-okú, yio si ma ṣọ́ ororì okú.
33Ogulutu ọfin yio dùn mọ ọ, gbogbo enia yio si ma tọ̀ ọ lẹhin, bi enia ainiye ti lọ ṣiwaju rẹ̀.
34E ha ti ṣe ti ẹnyin fi ntù mi ninu lasan! bi o ṣepe ni idahùn nyin eké kù nibẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.