Job 35

35
1ELIHU sọ pẹlu o si wipe,
2Iwọ rò pe eyi ha tọ́, ti iwọ wipe, ododo mi ni eyi niwaju Ọlọrun pe,
3Nitoriti iwọ wipe, Ère kini yio jasi fun ọ, tabi ère kili emi o fi jẹ jù ère ẹ̀ṣẹ mi lọ?
4Emi o da ọ lohùn ati awọn ẹgbẹ rẹ pẹlu rẹ.
5Ṣiju wò ọrun, ki o ri i, ki o si bojuwo awọsanma ti o ga jù ọ lọ.
6Bi iwọ ba ṣẹ̀ kini iwọ fi ṣe si i? tabi bi irekọja rẹ di pupọ, kini iwọ fi eyini ṣe si i?
7Bi iwọ ba si ṣe olododo, kini iwọ fi bùn u, tabi kili on ri gbà lati ọwọ rẹ wá?
8Ìwa buburu rẹ ni fun enia bi iwọ; ododo rẹ si ni fun ọmọ enia.
9Nipa ọ̀pọlọpọ ininilara nwọn mu ni kigbe, nwọn kigbe nitori apá awọn alagbara.
10Ṣugbọn kò si ẹniti o wipe, Nibo ni Ọlọrun Ẹlẹda mi wà, ti o fi orin fun mi li oru?
11Ti on kọ́ wa li ẹkọ́ jù awọn ẹranko aiye lọ, ti o si mu wa gbọ́n jù awọn ẹiyẹ oju ọrun lọ.
12Nigbana ni nwọn ke, ṣugbọn Ọlọrun kò dahùn nitori igberaga awọn enia buburu.
13Nitõtọ Ọlọrun kì yio gbọ́ asan, bẹ̃ni Olodumare kì yio kà a si.
14Bi o tilẹ ṣepe iwọ wipe, iwọ kì iri i, ọran idajọ mbẹ niwaju rẹ̀, ẹniti iwọ si gbẹkẹle.
15Ṣugbọn nisisiyi nitoriti ibinu rẹ̀ kò ti ṣẹ́ ọ niṣẹ, on kò ha le imọ̀ ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ bi?
16Nitorina ni Jobu ṣe ya ẹnu rẹ̀ lasan, o sọ ọ̀rọ di pupọ laisi ìmọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Job 35: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀