Job 4
4
Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni
(Job 4:1—14:22)
1NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
2Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ?
3Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le.
4Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera.
5Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀.
6Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ?
7Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri?
8Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na.
9Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun.
10Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka.
11Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.
12Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀.
13Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia.
14Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé.
15Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan.
16On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe:
17Ẹni kikú le jẹ olododo niwaju Ọlọrun, enia ha le mọ́ ju Ẹlẹda rẹ̀ bi?
18Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ.
19Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro.
20A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si.
21A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 4: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.