Job 6
6
1JOBU si dahùn o si wipe,
2A! a ba le iwọ̀n ibinujẹ mi ninu òṣuwọn, ki a si le igbe ọ̀fọ mi le ori òṣuwọn ṣọkan pọ̀!
3Njẹ nisisiyi, iba wuwo jù iyanrin okun lọ: nitorina li ọ̀rọ mi ṣe ntàse.
4Nitoripe ọfa Olodumare wọ̀ mi ninu, oró eyiti ọkàn mi mu; ipaiya-ẹ̀ru Ọlorun dotì mi.
5Kẹtẹkẹtẹ ìgbẹ a ma dún, nigbati o ba ni koriko, tabi ọdá-malu a ma dún sori ijẹ rẹ̀?
6A le jẹ ohun ti kò li adùn li aini iyọ̀, tabi adùn wà ninu funfun ẹyin?
7Ohun ti ọkàn mi kọ̀ lati tọ́, on li o dàbi onjẹ mi ti kò ni adùn.
8A! emi iba lè ri iberè mi gbà; ati pe, ki Ọlọrun le fi ohun ti emi ṣafẹri fun mi.
9Ani, Ọlọrun iba jẹ pa mi run, ti on iba jẹ ṣiwọ rẹ̀ ki o si ké mi kuro.
10Nigbana ni emi iba ni itunú sibẹ, ani emi iba mu ọkàn mi le ninu ibinujẹ mi ti kò da ni si: nitori emi kò fi ọ̀rọ Ẹni Mimọ́ nì sin ri.
11Kili agbara mi ti emi o fi dabá? ki si li opin mi ti emi o fi fà ẹmi mi gùn?
12Agbara mi iṣe agbara okuta bi, tabi ẹran ara mi iṣe idẹ?
13Iranlọwọ mi kò ha wà ninu mi: ọgbọn ha ti salọ kuro lọdọ mi bi?
14Ẹniti aya rẹ̀ yọ́ danu tan ni a ba ma ṣãnu fun lati ọdọ ọrẹ rẹ̀ wá, ki o má kọ̀ ibẹru Olodumare silẹ̀.
15Awọn ará mi ṣẹ̀tan bi odò ṣolõ, bi iṣàn gburu omi odò ṣolõ, nwọn ṣàn kọja lọ.
16Ti o dúdu nitori omi didì, ati nibiti òjo didì gbe lùmọ si.
17Nigbakũgba ti nwọn ba gboná, nwọn a si yọ́ ṣanlọ, nigbati õrùn ba mú, nwọn si gbẹ kurò ni ipò wọn.
18Iya ọ̀na wọn a si yipada sapakan, nwọn goke si ibi asan, nwọn si run.
19Ẹgbẹ ogun Tema nwoye, awọn ọwọ́-èro Seba duro de wọn.
20Nwọn dãmu, nitoriti nwọn ni abá; nwọn debẹ̀, nwọn si dãmu.
21Njẹ nisisiyi, ẹnyin dabi wọn; ẹnyin ri irẹ̀silẹ mi, aiya si fò nyin.
22Emi ha wipe, ẹ mu ohun fun mi wá, tabi pe, ẹ bun mi ni ẹ̀bun ninu ohun ini nyin?
23Tabi, ẹ gbà mi li ọwọ ọ̀ta nì, tabi, ẹ rà mi padà kuro lọwọ alagbara nì!
24Ẹ kọ́ mi, emi o si pa ẹnu mi mọ́; ki ẹ si mu mi moye ibiti mo gbe ti ṣìna.
25Wo! bi ọ̀rọ otitọ ti li agbara to! ṣugbọn kini aròye ibawi nyin jasi?
26Ẹnyin ṣebi ẹ o ba ọ̀rọ ati ohùn ẹnu ẹniti o taku wi, ti o dabi afẹfẹ.
27Ani ẹnyin ṣẹ́ gege fun alainibaba, ẹnyin si da iye le ọrẹ nyin.
28Nitorina ki eyi ki o tó fun nyin: ẹ ma wò mi! nitoripe o hàn gbangba pe: li oju nyin ni emi kì yio ṣeke.
29Emi bẹ̀ nyin, ẹ pada, ki o má ṣe jasi ẹ̀ṣẹ: ani ẹ si tun pada, are mi mbẹ ninu ọ̀ran yi.
30Aiṣedede ha wà li ahọn mi? njẹ itọwò ẹnu mi kò kuku le imọ̀ ohun ti o burujù?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 6: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.