Job 9
9
1JOBU si dahùn o si wipe,
2Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun?
3Bi o ba ṣepe yio ba a jà, on kì yio lè idá a lohùn kan ninu ẹgbẹrun ọ̀ran.
4Ọlọgbọ́n-ninu ati alagbara ni ipá li on; tali o ṣagidi si i, ti o si gbè fun u ri?
5Ẹniti o ṣi okè ni idi, ti nwọn kò si mọ̀: ti o tari wọn ṣubu ni ibinu rẹ̀.
6Ti o mì ilẹ aiye tìti kuro ni ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ si mì tìti.
7Ti o paṣẹ fun õrùn, ti on kò si là, ti o si dí irawọ̀ mọ́.
8On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun.
9Ẹniti o da irawọ̀ Arketuru, Orioni ati Pleiade ati iyàra pipọ ti gusu.
10Ẹniti nṣe ohun ti o tobi jù awari lọ, ani ohun iyanu laini iye.
11Kiyesi i, on kọja lọ li ẹ̀ba ọdọ mi, emi kò si ri i, o si kọja siwaju, bẹ̃li emi kò ri oju rẹ̀.
12Kiyesi i, o jãgbà lọ, tani yio fa a pada? tani yio bi i pe, kini iwọ nṣe nì?
13Ọlọrun kò ni fà ibinu rẹ̀ sẹhin, awọn oniranlọwọ ìgberaga a si tẹriba labẹ rẹ̀.
14Ambọtori emi ti emi o fi dá a lohùn, ti emi o fi má ṣa ọ̀rọ awawì mi ba a ṣawiye?
15Bi o tilẹ ṣepe mo ṣe olododo, emi kò gbọdọ̀ da a lohùn, ṣugbọn emi o gbadura ẹ̀bẹ mi sọdọ onidajọ mi.
16Bi emi ba si kepè e, ti on si da mi lohùn, emi kì yio si gbagbọ pe, on ti feti si ohùn mi.
17Nitoripe o fi ẹ̀fufu nla ṣẹ mi tutu, o sọ ọgbẹ mi di pipọ lainidi.
18On kì yio jẹ ki emi ki o fà ẹmi mi, ṣugbọn o fi ohun kikorò kún u fun mi.
19Bi mo ba sọ ti agbara, wò o! alagbara ni, tabi niti idajọ, tani yio da akoko fun mi lati rò?
20Bi mo tilẹ da ara mi lare, ẹnu ara mi ni yio dá mi lẹbi; bi mo wipe, olododo li emi, yio si fi mi hàn ni ẹni-òdi.
21Olõtọ ni mo ṣe, sibẹ emi kò kiyesi ẹmi mi, ìwa mi li emi iba ma gàn.
22Ohun kanna ni, nitorina ni emi ṣe sọ ọ: on a pa ẹni-otitọ ati enia buburu pẹlu.
23Bi jamba ba pa ni lojijì, yio rẹrin idanwo alaiṣẹ̀.
24A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani?
25Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire.
26Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ.
27Bi emi ba wipe, emi o gbagbe aro ibinujẹ mi, emi o fi ọkàn lelẹ̀, emi o si rẹ̀ ara mi lẹkun.
28Ẹ̀ru ibinujẹ mi gbogbo bà mi, emi mọ̀ pe iwọ kì yio mu mi bi alaiṣẹ̀.
29Bi o ba ṣepe enia buburu li emi, njẹ kili emi nṣe lãlã lasan si!
30Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́,
31Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira.
32Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ.
33Bẹ̃ni kò si alatunṣe kan lagbedemeji wa, ti iba fi ọwọ rẹ̀ le awa mejeji lara.
34Ki on sa mu ọ̀pa rẹ̀ kuro lara mi, ki ìbẹru rẹ̀ ki o má si ṣe daiya fò mi.
35Nigbana ni emi iba sọ̀rọ, emi kì ba si bẹ̀ru rẹ̀; ṣugbọn kò ri bẹ̃ fun mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Job 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.