Jon 4:10-11

Jon 4:10-11 YBCV

Nigbana ni Oluwa wipe, Iwọ kẹdùn itakùn na nitori eyiti iwọ kò ṣiṣẹ, bẹ̃li iwọ kò mu u dagbà; ti o hù jade li oru kan ti o si kú li oru kan. Ki emi ki o má si da Ninefe si, ilu nla nì, ninu eyiti jù ọ̀kẹ-mẹfa enia wà ti kò le mọ̀ ọtun mọ̀ osì ninu ọwọ́ wọn, ati ọ̀pọlọpọ ohun-ọsìn?