Joṣ 2
2
Joṣua Rán Àwọn Amí Lọ sí Jẹriko
1JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
2A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò.
3Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò.
4Obinrin na si mú awọn ọkunrin meji na, o si fi wọn pamọ́; o si wi bayi pe, Awọn ọkunrin kan wá sọdọ mi, ṣugbọn emi kò mọ̀ ibi ti nwọn ti wá.
5O si ṣe li akokò ati tì ilẹkun ẹnubode, nigbati ilẹ ṣú, awọn ọkunrin na si jade lọ: ibi ti awọn ọkunrin na gbé lọ, emi kò mọ̀: ẹ lepa wọn kánkán; nitori ẹnyin o bá wọn.
6Ṣugbọn o ti mú wọn gòke àja ile, o si fi poroporo ọ̀gbọ ti o ti tòjọ soke àja bò wọn mọlẹ.
7Awọn ọkunrin na lepa wọn li ọ̀na ti o lọ dé iwọ̀do Jordani: bi awọn ti nlepa wọn si ti jade lọ, nwọn tì ilẹkun ẹnubode.
8Ki nwọn ki o tó dubulẹ, o gòke tọ̀ wọn lọ loke àja;
9O si wi fun awọn ọkunrin na pe, Emi mọ̀ pe OLUWA ti fun nyin ni ilẹ yi, ati pe ẹ̀ru nyin bà ni, ati pe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori nyin.
10Nitoripe awa ti gbọ́ bi OLUWA ti mu omi Okun Pupa gbẹ niwaju nyin, nigbati ẹnyin jade ni Egipti; ati ohun ti ẹnyin ṣe si awọn ọba meji ti awọn Amori, ti mbẹ ni ìha keji Jordani, Sihoni ati Ogu, ti ẹnyin parun tútu.
11Lọgán bi awa ti gbọ́ nkan wọnyi, àiya wa já, bẹ̃ni kò si sí agbara kan ninu ọkunrin kan mọ́ nitori nyin; nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin, on li Ọlọrun loke ọrun, ati nisalẹ aiye.
12Njẹ nitorina, emi bẹ̀ nyin, ẹ fi OLUWA bura fun mi, bi mo ti ṣe nyin li ore, ẹnyin o ṣe ore pẹlu fun ile baba mi, ẹnyin o si fun mi li àmi otitọ:
13Ati pe ẹnyin o pa baba mi mọ́ lãye, ati iya mi, ati awọn arakunrin mi, ati awọn arabinrin mi, ati ohun gbogbo ti nwọn ní, ki ẹnyin si gbà ẹmi wa lọwọ ikú.
14Awọn ọkunrin na da a lohùn pe, Ẹmi wa ni yio dipò ti nyin, bi ẹnyin kò ba fi ọ̀ran wa yi hàn; yio si ṣe, nigbati OLUWA ba fun wa ni ilẹ na, awa o ṣe ore ati otitọ fun ọ.
15Nigbana li o fi okùn sọ̀ wọn kalẹ li oju-ferese: nitoriti ile rẹ̀ wà lara odi ilu, on a si ma gbé ori odi na.
16O si wi fun wọn pe, Ẹ bọ sori òke, ki awọn alepa ki o má ba le nyin bá; ki ẹnyin si fara nyin pamọ́ nibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa yio fi pada: lẹhin na ẹ ma ba ọ̀na ti nyin lọ.
17Awọn ọkunrin na wi fun u pe, Ara wa o dá niti ibura rẹ yi, ti iwọ mu wa bú.
18Kiyesi i, nigbati awa ba dé inu ilẹ na, iwọ o so okùn owú ododó yi si oju-ferese ti iwọ fi sọ̀ wa kalẹ: iwọ o si mú baba rẹ, ati iya rẹ, ati awọn arakunrin rẹ, ati gbogbo ara ile baba rẹ, wá ile sọdọ rẹ.
19Yio si ṣe, ẹnikẹni ti o ba jade lati inu ilẹkun ile rẹ lọ si ode, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori ara rẹ̀, awa o si wà li aijẹbi: ati ẹnikẹni ti o ba wà pẹlu rẹ ni ile, ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà li ori wa, bi ẹnikẹni ba fọwọkàn a.
20Bi o ba si sọ ọ̀ran wa yi, nigbana ni ara wa o dá niti ibura rẹ ti iwọ mu wa bú yi.
21O si wipe, Gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin, bẹ̃ni ki o ri. O si rán wọn lọ, nwọn si lọ: o si so okùn ododó na si oju-ferese.
22Nwọn si lọ, nwọn si dé ori òke, nwọn si gbé ibẹ̀ ni ijọ́ mẹta, titi awọn alepa fi pada: awọn alepa wá wọn ni gbogbo ọ̀na, ṣugbọn nwọn kò ri wọn.
23Bẹ̃li awọn ọkunrin meji na pada, nwọn si sọkalẹ lori òke, nwọn si kọja, nwọn si tọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wá; nwọn si sọ ohun gbogbo ti o bá wọn fun u.
24Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Joṣ 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.